O ma ṣe o! Wọn gun Alufa lọbẹ pa nibi to ti lọ la ija tọkọ-taya l’Osogbo - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, January 3, 2025

O ma ṣe o! Wọn gun Alufa lọbẹ pa nibi to ti lọ la ija tọkọ-taya l’Osogbo


‘Ẹ ba wa gbe wọn, a ti pari ija’, wọnyi lọrọ to n jade lẹnu tọkọ-taya kan ti wọn sọ pe wọn gun Alufa ijọ kan, Biṣọọbu Shina Olaribigbe lọbgẹ titi to fi dakẹ.

Ọjọbọ, ọjọ keji, oṣu Kinni, ọdun 2025 ni iṣẹlẹ ọhun waye niluu oSogbo, ipinlẹ Osun.

Alufa Olaribigbe ni olori ijọ Rapture Empowerment International, to wa niluu Osogbo.

Gẹgẹ bi iroyin to tẹ wa lọwọ ṣe sọ, wọn ni ija ni Olaribigbe n la tọkọ-taya naa, ko to di pe ọkọ obinrin naa fa ọbẹ yọ, to si fi gun pasitọ titi to fi doloogbe.

Kii ṣe igba akọkọ ree ti wọn sọ pe Olaribigbe yoo maa pari ija laarin tọkọ-taya ti wọn ko fi orukọ wọn sita naa, ṣugbọn ti eyi to ṣẹlẹ gbẹyin yii gbọna miran yọ.

Ṣọọṣi Olaribigbe ni wọn sọ pe obinrin naa n lọ, koda, ti wọn sọ pe iyaale ile ọhun ni ogbufọ (interpreter) ijọ naa. Lati bi ọjọ meloo sẹyin ni wọn sọ pe obinrin naa ti wa lori idubulẹ aisan, eyi lo mu ki alufaa naa lọ sile rẹ lati ṣabẹwo sii.

Wọn ni ko pẹ ti Olaribigbe debẹ, ni ọkọ obinbinrin ọhun de, to si fẹẹ fura pe o ṣee ṣe ki awọn mejeeji maa ni nnkan papọ.

Loju ẹsẹ ni wọn lo ti ba iyawo rẹ wọya ija, ti wọn si ni alufaa naa n pẹtu si wọn ninu.

Pẹlu ibinu ni wọn sọ pe ọkunrin naa fi lọ fa ọbẹ yọ, to si gun Olaribigbe ni igba-aya, tiyẹn si gbabẹ sọda sọrun alakeji loju ẹsẹ.

Ere ni wọn pe e, afi bọrọ ọhun ṣe di ariwo nla.

Awọn ara agbegbe naa ni wọn ranṣẹ sawọn ọlọpaa to wa fọwọ ofin mu tọkọ-taya naa, ti wọn si gbe oku Olaribigbe lọ mọṣuari ọsibitu awọn olukọni ti UNIOSUN.

Yemisi Opalola to jẹ agbẹnusọ ọlọpaa ipinlẹ Osun nigba to n fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ ṣalaye pe ọwọ ti tẹ tọkọ taya naa, wọn si ti n fọrọ wa wọn lẹnu wo.

O jẹ ko di mimọ pe tọkọtaya ọhun ko jọ gbe papọ labẹ orule kan naa, ati pe ofin ko tii tu wọn ka.

Opalola ni ori bẹẹdi obinrin naa ni Alufa Olaribigbe jokoo si lasiko ti ọkọ rẹ wọle de, eyi to fa ibinu to fi gun un pẹlu ọbẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI