Nnkan de! Alakoso ẹka eto iṣiro owo nile iwosan FMC gbẹmi ara rẹ l'Abẹokuta - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, January 21, 2025

Nnkan de! Alakoso ẹka eto iṣiro owo nile iwosan FMC gbẹmi ara rẹ l'Abẹokuta


Titi di asiko ti a pari akojọpọ iroyin yii ni iroyin iku alakoso agba lẹka eto iṣiro owo nile iwosan ijọba apapọ, iyẹn Federal Medical Centre to wa niluu Abeokuta, ipinlẹ Ogun, Adeniyi Oluwaseun ṣi n jẹ kayeefi.

Iroyin to tẹ wa lọwọ sọ pe ọkunrin naa gbẹmi ara rẹ ni, pẹlu bi wọn ṣe lo lọ binu ko si kọnga, to si gbabẹ ku.

Ohun ti a gbọ ni pe irọlẹ ọjọ Aiku to kọja yii ni Adeniyi gbẹmi ara rẹ nile rẹ to n gbe lagbegbe Obantoko niluu Abeokuta.

Ko si nnkan meji to n jẹ ki iku baba ọlọmọ mẹta naa maa ya awọn mọlẹbi rẹ lẹnu, bi ko ṣe ti ọmọ rẹ ti wọn lo n palẹmọ lati ṣe igbeyawo ni nnkan bi ọsẹ meloo si asiko yii.

AWIKONKO gbọ pe ko tii ju bi iṣẹju diẹ ti ọkunrin naa jẹ ounjẹ alẹ tan, ko to lọ bẹ sinu kọnga.

Bo tilẹ jẹ pe a ko le fidi rẹ mulẹ, sibẹ ohun ti a gbọ ni pe oloogbe naa ni ipenija ọpọlọ tẹlẹ, to si n gba itọju loorekoore.

Wọn ni igba ti awọn ẹbi oloogbe naa fẹẹ tilẹkun inu ile lati lọ sun, ni wọn pe e, ṣugbọn ti wọn ko gburo rẹ, eyi lo jẹ ki wọn bẹrẹ sii wa kaakiri.

Nibi ti wọn ti n wa ni awọn kan ti kofiri rẹ ninu kọnga, ti wọn si pariwo sita fawọn araadugbo.

Nipa iranlọwọ awọn ara adugbo naa ni wọn fi gbe oku rẹ jade, ti wọn si gbe e lọ si mọṣuari.

Agbẹnusọ agba nile iwosan FMC naa, Segun Orisajo nigba to n sọrọ jẹ ko di mimọ pe ibanujẹ ni iku oloogbe naa jẹ fun wọn.

Orisajo ni awọn ko lero pe ọkunrin to fi ara jin fun iṣẹ naa le tete jade laye, nitori pe gbogbo ọsẹ to kọja lo fi wa lẹnu iṣẹ, to si n ṣiṣẹ takuntakun.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI