Nko fẹgbẹ oṣelu APC silẹ o – El-Rufai pariwo sita - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, January 6, 2025

Nko fẹgbẹ oṣelu APC silẹ o – El-Rufai pariwo sita


Gomina tẹlẹ nipinlẹ Kaduna, Malam Nasir El-Rufai, ti sọ pe ko si otitọ kankan ninu iroyin to n kaakiri wi pe oun ti fẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress (APC) silẹ lati darpọ mọ ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party (PDP).

O ni iroyin ẹlẹjẹ pọmbele ti ko lẹsẹ ni wọn n gbe kaakiri lati fi ba oun lorukọ jẹ.

Ọkan lara awọn alabaṣiṣẹpọ El-Rufai lo sọ eyi di mimọ lasiko to n farahan lori ẹrọ amohunmaworan Channels laipẹ yii, to si ni awọn ọbayejẹ lo wa nidi iroyin ẹlẹjẹ naa.

Ẹni naa sọ pe pẹlu ipo ti El-Rufai di mu ninu oṣelu, ko ṣee se lati darapọ mọ PDP lai kede sita.

Nigba toun funra rẹ n fidi rẹ mulẹ loju opo ‘X’ rẹ, El-Rufai sọ pe kawọn eeyan ma ṣe gba iroyin naa gbọ, nitori pe iroyin ẹlẹjẹ lasan ni.

Bakan naa lo jẹ ko di mimọ pe oun ti sọ fun agbẹjọro oun lati gbe igbesẹ labẹ ofin lori awọn to n gbe ayederu iroyin ọhun kaakiri.

“Ẹ dakun, ẹ ma ṣe gba iroyin ẹlẹjẹ ati iroyin ti wọn n gbe kaakiri nipa ọrọ oṣelu mi. Mo ti fa awọn to n ṣagbatẹru iroyin naa le agbẹjọro mi lọwọ lati gbe igbesẹ to tọ labẹ ofin,” El-Rufai lo sọ eyi lọjọ Aiku to kọja.


No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI