Nitori irẹsi ọdun, Daniel gun Christian nigo ọti pa lọjọ ọdun - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, January 3, 2025

Nitori irẹsi ọdun, Daniel gun Christian nigo ọti pa lọjọ ọdun


Kayeefi lọrọ ọdọmọkunrin, ẹni ọgbọn ọdun kan, Daniel Onyejekwe ṣi n jẹ fun ọpọ awọn eeyan, lori bo ṣe gun ọrẹ rẹ, Christian pa lori irẹsi ti wọn n ja si.

Agbẹnusọ ọlọpaa ipinlẹ Delta, SP Bright Edafe, lo fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ, to si lọwọ ti tẹ Daniel, ẹni to ti wa lahamọ nibi ti wọn ti n fọrọ wa a lẹnu wo.

Edafe sọ pe awọn mejeeji yii ni wọn wọya ija lori irẹsi ọdun, ti wọn si ṣe awọn leṣe gidigidi, nibi ti Christian ti gba ekuru jẹ lọwọ ẹbọra.

A gbọ pe agbegbe kan ti wọn pe ni Ogwanja to wa niluu Sapele niṣẹlẹ ọhun ti waye.

Wọn ni awọn kan lo n pin irẹsi ọdun fawọn eeyan lopopona Boyo, Ogwanja to wa ni Sapele, nibẹ ni awọn mejeeji ti bẹrẹ sii ja si irẹsi abọ kan.

Iroyin sọ pe pẹlu ibinu ni Daniel fi fa igo yọ, to si fi gun Christian lọna to pọ, eyi to mu ki ẹjẹ maa da ṣoroṣoro lara rẹ.

Ko pẹ rara ti wọn ni Christian fidi janlẹ, to si ku loju ẹsẹ.

Awọn ẹṣọ aabo Fijilante to wa nibẹ ni wọn mu Daniel silẹ, nigba to fẹ maa salọ, ko to di pe wọn lọ fa a le awọn ọlọpaa lọwọ.

Ọkan lara awọn ti iṣẹlẹ naa ṣoju wọn ṣalaye pe;

“Ẹnikan lo n pin irẹsi lopopona Boyo, Ogwanja ni Sapele. Nibẹ ni Christian ati Onyejekwe ti bẹrẹ sii fa irẹsi naa mọ ara wọn lọwọ, eyi to pada di ija nla laarin wọn.

“Daniel fa igo yọ, o si fi gun Christian lọpọ igba. Ko to di pe awọn Fijilante sare gbe e lọ si ile iwosan, wọn lo ti dakẹ.”

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI