Lẹyin ọdun mẹrin ataabọ lahamọ, wọn da ẹjọ iku fun ọrẹ mẹrin l'Ekiti - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, January 31, 2025

Lẹyin ọdun mẹrin ataabọ lahamọ, wọn da ẹjọ iku fun ọrẹ mẹrin l'Ekiti


Ariwo 'haaaa' lo gba ẹnu awọn oluworan ile-ẹjọ l'Ọjọbọ to kọja yii, nigba ti ile-ẹjọ giga paṣẹ pe ki wọn lọ yẹgi fun ọrẹ mẹrin ti wọn fẹsun idigunjale kan nipinlẹ Ekiti.


Onidajọ Lekan Ọlatawura to gbe idajọ naa kalẹ sọ pe awọn ẹri to wa niwaju oun, eyi ti wọn fi tako awọn ọrẹ mẹrin naa fidi rẹ mulẹ pe ogbologbo adigunjale ni wọn ati pe wọn ko yẹ lati wa laarin awujọ.

Awọn mẹrin naa ni; Oyedele Oluwatobi, ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn; Damilola Christopher, ẹni ọgbọn ọdun; Tope Ojo, ẹni ọdun mẹtadinlogoji; ati Temitope Aderopo, ẹni ọdun mẹtadinlogoji.

AWIKONKO rii gbọ pe ọjọ kẹta, oṣu Kẹjọ, ọdun 2021 ni awọn mẹrẹẹrin gbimọ papọ lati digunjale ladugbo kan ti wọn n pe ni Ilu-titun, eyi to wa niluu Ikere Ekiti, ipinlẹ Ekiti.

Ẹsun mẹrin ọtọọtọ to nii ṣe pẹlu igbimọ papọ ati idigunjale ni wọn fi kan wọn lọjọ ti wọn foju ba ile-ẹjọ ninu oṣu kẹrin ọdun 2024.

Lọjọ naa, agbefọba to tako wọn niwaju ile-ẹjọ ṣalaye pe niṣe lawọn mẹrẹẹrin gbimọ papọ pẹlu ibọn, ti wọn si digun ja awọn ti wọn pe orukọ wọn ni Idowu Damilọla, Ganiyu Abimbọla, Idowu Tolulọpẹ, ati Taye Adegboye lole.

Owo ti ko din ni ẹgbẹrun mẹrindinlogoje ni wọn fi ibọn gba lọwọ awọn ti wọn ja lole; yatọ si eyi, wọn tun gba awọn dukia bii ẹrọ agbanasara alagbeka ti wọn fi n gba ina sori foonu, kọmputa alagbeka, ẹrọ amohundungbẹmu, foonu rẹpẹtẹ ati ẹṣọ ara.

Ọkan lara awọn ti wọn ja lole, Idowu Damilọla, to jẹri tako wọn niwaju ile-ẹjọ sọ pe oju oorun loun wa ti awọn adigunjale naa fi wọnu ile tọ oun.

Damilọla sọ pe boun ṣe gburo wọn, loun ti sare gun ori aja lati farapamọ, ṣugbọn to sọ pe oun pada sọkalẹ lati yọju si wọn nigba ti wọn dunkooko lati yinbọn pa aburo oun.

Adajọ naa wa sọ pe gbogbo ẹri toun ti gba lori ẹsun naa kọja ohun ti wọ le gboju fo, tabi foju aanu wo wọn, to si paṣẹ pe ki wọn lọ yẹgi fun wọn, titi digba ti ẹmi yoo fi bọ lara wọn.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI