Sẹnetọ Oluremi Tinubu to jẹ iyawo Aarẹ Bola Ahmed ti ṣe ifilọlẹ ọsibitu alara gbayida ti Gomina Abdulrahman Abdulrazaq ipinlẹ Kwara dawọ le.
Lara rẹ ni ile iwosan igbalode ti Gomina AbdulRazaq sọ lorukọ Sẹnetọ Oluremi Tinubu Hospital, niluu Ilorin.
Ọjọru, ọsẹ yii ni wọn ṣe ifilọlẹ naa, lati fi mọ pataki awọn igbesẹ iyawo aarẹ ninu agbelarugẹ iṣọkan laaarin ọmọ Naijiria.
Ninu atẹjade ti Olayinka Fafoluyi to jẹ amugbalẹgbẹ agba pataki fun gomina lori eto iroyin igbalode fi sita, o ni igbesẹ naa ni lati jẹ ki gbogbo araalu ni anfaani si eto ìlera to pe ye.
No comments:
Post a Comment