Ijọba Kwara tun bẹrẹ kikọ ibudo imọ ẹrọ igbalode tuntun niluu Shonga - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Sunday, January 19, 2025

Ijọba Kwara tun bẹrẹ kikọ ibudo imọ ẹrọ igbalode tuntun niluu Shonga


Ijọba ipinlẹ Kwara labẹ iṣakoso Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti bẹrẹ kikọ ibudo imọ ẹrọ igbalode ti awọn oloyinbo n pe ni Information, Communication and Technology (ICT) tuntun siluu Shonga, ijọba ibilẹ Edu.

Ileeṣẹ kan ti wọn pe ni Skylat-One Nigeria Ltd ni ijọba Kwara gbe iṣẹ naa le lọwọ, ko le tete pari.

Ọkunrin kan ti wọn pe orukọ rẹ ni Adegboyega Akinwumi, ni wọn lo ni ileeṣẹ Skylat-One Nigeria Ltd.

Owo ti ko din ni N242 miliọnu naira ni yoo pari akanṣe iṣẹ naa, gẹgẹ bi Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ṣe buwọlu.

Nigba to n ṣalaye nibi ifilọle to waye laipẹ yii, Kọmiṣanna feto okoowo ati agbekalẹ imọ ẹrọ, Ọnarebu Damilola Yusuf Adelodun, ṣalaye pe idagbasoke awọn akanṣe iṣẹ, paapaa imọ ẹrọ jẹ ijọba ipinlẹ naa logun pupọ.

Adelodun ni eyi yoo tun pese iṣẹ rẹpẹtẹ fun awọn ọdọ, lati mu ilọsiwaju ba eto ọrọ aje.

Bakan naa lo ni agbekalẹ tuntun ọhun yoo mu irọrun ba agbegbe okoowo ṣiṣe ati idaṣẹsilẹ laarin ilu.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI