Ijọba Kwara ṣafihan aragba-yamu-yamu ibudo imọ ẹrọ igbalode ti wọn fẹẹ kọ siluu Shonga - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, January 22, 2025

Ijọba Kwara ṣafihan aragba-yamu-yamu ibudo imọ ẹrọ igbalode ti wọn fẹẹ kọ siluu Shonga


Ijọba ipinlẹ Kwara labẹ iṣakoso Gomina Abdulrahman Abdulrazaq ti ṣafihan bi gbọngan imọ ẹrọ igbalode, ICT Hub ti wọn fẹẹ bẹrẹ kikọ rẹ siluu Shonga, ijọba ibilẹ Edu.

Miliọnu 240 ni ijọba Kwara sọ pe wọn yoo fi kọ gbọngan naa, lati ro awọn ọdọ lagbara ni lẹka imọ ẹrọ igbalode.

Ultramodern Shonga Information, Communication and Technology (ICT) ni wọn pe agbekalẹ naa to jẹ ti Gomina Abdulrahman Abdulrazaq.

Ileeṣẹ Skylat-One Nigeria Ltd., to jẹ ti Onimọ-ẹrọ Adeboyega Akinwumi, ni agbaṣẹṣe ti yoo mojuto akanṣe iṣẹ naa.

Ninu atẹjade ti amugbalẹgbẹ agba pataki fun gomina lori eto iroyin igbalode, Olayinka Fafoluyi fi sita, o ni agbekalẹ naa waye lẹyìn ọsẹ diẹ ti gomina ṣeleri lati pari gbọngan imọ ẹrọ igbalode ti Ilorin Emirate Descendants Progressive Union (IEDPU) tech hub to n lọ lọwọ.






No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI