Ileeṣẹ to n ri seto iṣuna nipinlẹ Kwara ti parọwa si gbogbo oṣiṣẹ fẹyinti patapata lati lọ ṣe iforukọsilẹ tuntun, bi wọn ba fẹẹ gba owo ifẹyinti wọn.
Wọn ni ileeṣẹ to n ri sọrọ iforukọsilẹ araalu, Kwara State Residents Registration Agency (KWSRRA) lo n ṣagbatẹru eto iforukọsilẹ naa, nibi si ni wọn yoo ti forukọsilẹ fun idanimọ.
Nigba to n sọrọ, lọmiṣanna feto iṣuna, Ọmọwe Hauwa Nuru sọ pe yatọ si pe wọn n ṣe iforukọsilẹ naa nipa eto aabo ati agbekalẹ, yoo tun ṣe iranwọ lati jẹ ki wọn le gba owo oṣu ifẹyinti ati ajẹẹlẹ lati ọdun 2011.
No comments:
Post a Comment