Lojuna lati ṣagbelarugẹ fun eto imọtoto ayika ati agbegbe, leyi ti yoo le oniruuru ajakalẹ arun ati aisan jinna saarin, ijọba ipinlẹ Kwara ti sọ pe eto gbale-gbata yoo waye lopin ọsẹ yii.
Ọjọ Abamẹta, ọjọ karundinlọgbọn, oṣu Kinni ọdun ti a wa yii ni eto ọhun yoo waye kaakiri ipinlẹ naa.
Aarin agogo meje si mẹwaa owurọ ni eto ohun yoo fi waye, nibi ti gbogbo araalu yoo ti ṣe itọju ayika ati agbegbe wọn.
Kii ṣe igba akọkọ ree ti eto ọhun yoo maa waye, bẹẹ si ni ijọba Kwara mu eto ọhun lọkukudun, ninu akitiyan lati gbogun ti ajakalẹ arun.
Ninu atẹjade ti Shakirat Muritala to jẹ akọwe iroyin ileeṣẹ to n ṣabojuto eto ayika fi sita l'Ọjọru, o ni dandan ni araalu farajin fun eto imọtoto ayika ati agbegbe wọn.
O ni bi wọn ṣe n ṣe itọju ayika ati agbegbe ile ti wọn n gbe, naa ni ki wọn ma ṣe gbagbe ayika ati agbegbe ibi ti wọn ti n ṣiṣẹ oojọ wọn naa.
Atẹjade ọhun fi kun un pe ko nii si igbokegbodo ọkọ lasiko naa kaakiri igboro ati igberiko, bẹẹ si ni awọn eeyan ko gbọdọ rin kaakiri lai jẹ pe wọn n ṣe itọju ayika wọn.
Siwaju sii ni ijọba jẹ ko di mimọ pe awọn ọkọ to n da ilẹ nu yoo maa lọ kaakiri lati ko awọn idọti ti wọn gba jọ lati lọ da wọn nu s'awọn ibudo idalẹsi tijọba buwọ lu.
"Ẹsẹ ni lati da ilẹ tabi idọti si opopona, ẹgbẹ titi, inu kọta ti omi n gba, inu odo ati awọn ibi ti ijọba ko fọwọ si, to si ni ijiya labẹ ofin to de ayika ati agbegbe," ileeṣẹ eto ayika jẹ ko di mimọ fun araalu.
"Bakan naa, oniruuru erongba lati di awọn aṣoju ijọba lọwọ lati ṣiṣẹ wọn ni a ko nii fọwọ yẹpẹrẹ mu, ẹnikẹni tọwọ ba tẹ wi pe o n gbiyanju lati dena awọn aṣoju ijọba lati ṣiṣẹ wọn yoo foju winna ofin."
No comments:
Post a Comment