Ijọba ipinlẹ Kwara labẹ iṣakoso Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti kede pe iṣakoso oun ti gbe ọkọ bọọsi ọfẹ kalẹ fun gbogbo ile-ẹkọ giga, paapaa awọn akẹkọọ fasiti tiluu Ilọrin (UNILORIN) ati tipinlẹ Kwara (KWASU).
Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, ileeṣẹ Business Innovation and Technology lo ṣagbatẹru eto igbokegbodo okọ bọọsi ọfẹ naa fawọn akẹkọọ wọnyi.
Wọn ni gbogbo awọn akẹkọọ naa ti wọn ṣẹṣẹ n bọ lati ile ọdun ni wọn yoo lanfaani lati wọ bọọsi ọhun pada sile ẹkọ wọn lai san owo kankan.
Awọn agbegbe bii ile ẹkọ girama Queen Elizabeth ati ibudokọ Soludero to wa ni Post Office, Ilorin ni awọn bọọsi ọhun yoo duro si, fawọn akẹkọọ naa lati pada sile ẹkọ wọn nirọrun.
Ọnarebu Damilola Yusuf Adelodun to jẹ kọmiṣanna ileeṣẹ to ṣagbatẹru eto ọhun nigba to n sọrọ, ṣalaye pe ijọba dide iranwọ yii lati gbaruku ti awọn akẹkọọ, ki eto ẹkọ wọn le lọ bo ti yẹ.
No comments:
Post a Comment