Ijọba Kwara gba olukọ agba tuntun to din diẹ lẹgbẹrun meji - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Sunday, January 19, 2025

Ijọba Kwara gba olukọ agba tuntun to din diẹ lẹgbẹrun meji


Ko din ni ẹgbẹrun mejidinnigba (1800) olukọ tijọba ipinlẹ Kwara gba laipẹ yii fun ise olukọ agba.

 Awọn olukọ naa ni yoo ṣiṣẹ labẹ ajọ 
Teaching Service Commission (TESCOM) lati mu itẹsiwaju ba eto ẹkọ.

Yatọ si awọn olukọ naa, ijọba tun buwọlu awọn oṣiṣẹ ọgọrun kan, ati oṣiṣẹ aabo igba lati mu eto aabo to peye wa layika eto ẹkọ.

Kaakiri awọn ile ẹkọ girama to wa laarin ilu, paapaa awọn igberiko to wa nijọba ibilẹ mẹrindinlogun ipinlẹ naa ni wọn yoo ti ṣiṣẹ. 

Alaga ajọ TESCOM nipinlẹ naa, Mallam Bello Tauheed Abubakar nigba to n sọrọ, jẹ ko di mimọ pe itakun oju opo ti awọn eeyan yoo ti forukọsilẹ ko ni pẹ ẹ jade.

Abubakar sọ pe gbogbo awọn to fẹẹ ṣiṣẹ naa yoo ni lati forukọsilẹ lori ayelujara, ati pe wọn gbọdọ ni iwe ẹri “B.Ed, BSc. Ed, B.A. Ed, BSc, to fi mọ PGDE tabi NCE.”

“Awọn ti ko ba ni eyikeyi ninu awọn iwe ẹri wọnyi ni a ko nii pe fun idanwo,” o ṣalaye bẹẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI