Ijọba Kwara bẹrẹ idanilẹkọọ fawọn araalu ti wọn fẹẹ ro lagbara - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, January 24, 2025

Ijọba Kwara bẹrẹ idanilẹkọọ fawọn araalu ti wọn fẹẹ ro lagbara


Gbogbo eto lo ti fẹẹ de ipari bayii fun ijọba ipinlẹ Kwara lati ṣe eto ironilagbara fun awọn araalu, paapaa awọn ọdọ.

Ọna ara ni eto irolagbara naa, eyi ti Gomina Abdulrahman Abdulrazaq kede rẹ faraalu bi ọdun 2024 ṣe n lọ si opin yoo gba waye, lori bi ijọba ṣe sọ pe ẹgbẹẹgbẹrun araalu ni yoo jẹ ninu anfaani naa.

Ọjọbọ to kọja ni eto idanilẹkọọ bẹrẹ fun gbogbo awọn to yege ninu eto iforukọsilẹ fun irolagbara naa.

Igbakeji olori awọn oṣiṣẹ gomina, ẹni ti tun jẹ alaga igbimọ eto irolagbara naa, Ọmọọbabinrin Bukola Babalola fidi ọrọ naa mulẹ ninu atẹjade to fi ranṣẹ s'awọn akọroyin l'Ọjọbọ to kọja.

Ọmọọbabinrin Babalola jẹ ko di mimọ pe ijọba ko nii fi ọrọ oṣelu mu awọn ti yoo jẹ anfaani naa, nitori pe aṣoju ipinlẹ naa ni gomina, kii sii ṣe fun ẹgbẹ oṣelu kan ṣoṣo.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI