Ijọba bẹrẹ tita jaala epo ni ẹgbẹta naira ni Borno - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Saturday, January 4, 2025

Ijọba bẹrẹ tita jaala epo ni ẹgbẹta naira ni Borno


Gomina ipinlẹ Borno, Babagana Zulum, ti kede pe ijọba oun ti bẹrẹ sii ta jaala epo kan ni ẹgbẹta naira, iyẹn 600naira fun awọn agbẹ.

Zulum sọ pe awọn agbẹ to wa lawọn agbegbe ti awọn agbesunmọmi Boko Haram ti ṣọṣẹ ni wọn yoo jẹ anfaani naa, lojuna lati ṣe iranwọ fun wọn.

Ninu atẹjade ti amugbalẹgbẹ pataki fun gomina lori eto iroyin igbalode, Abdulrahman Bundi fi sita loni, ọjọ Satide, ọjọ kẹrin, oṣu Kinni, ọdun 2025, o ni Zulum ṣe ikede naa nirọlẹ ọjọ Ẹti to kọja.

Zulum kede jija owo jaala epo naa walẹ lasiko to fi awọn ajilẹ, ohun ọgbin ati awọn irinṣẹ inu oko ta awọn agbẹ ti ko din ni ẹgbẹrun marun-un lọrẹ niluu Bawa, iyẹn nibi ti awọn agbesunmọmi Boko Haram ti ṣọṣẹ.

O ni ẹgbẹrun kan naira si ẹgbẹrun kan le nigba naira ni wọn n ta jaala epo kan niluu Maiduguri, ṣugbọn ni bayii, ijọba oun yoo bẹrẹ sii ta a ni ẹgbẹta naira bayii.

Nigba to n sọrọ, Zulum ṣalaye pe igbesẹ naa ni lati mu ẹru wiwo nipa eto iṣuna ti awọn agbẹ n koju kuro, paapaa lawọn agbegbe ti wọn ti koju oniruuru iṣoro eto ọrọ aje ati ilu bibajẹ, eyi tawọn agbesunmọmi ti ṣe kọja.

O ni ọkan pataki lara awọn iṣoro ti awọn agbẹ n koju ni ti ọrọ owo jaala epo to n lọ soke ni gbogbo igba, eyi to ni awọn gbọdọ wa ọna abayọ si.

O wa kede pe ijọba oun yoo bẹrẹ sii ra epo pamọ, lati maa ta a fun awọn agbẹ lowo ti ko gara. O ni ẹgbẹta naira, iyẹn 600naira lawọn yoo maa ta a, dipo ẹgbẹrun kan le nigba naira ti wọn n ta jaala epo niluu Maiduguri.

Siwaju sii ni gomina naa jẹ ko di mimọ pe Kọmiṣanna feto agbẹ yoo maa ṣiṣẹ papọ pẹlu ọga ologun lati rii daju pe epo naa n de ọdọ awọn agbẹ nilu Bawa laipẹ.

Nibi eto naa ni Zulum ti pin ẹgbẹrun meji baagi ajilẹ, ẹrọ omi ẹgbẹrun kan, to fi mọ awọn ohun elo ninu oko miran to le ni ẹgbẹrun mẹrin.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI