Beeyan ba gun ẹṣin lọkan awọn ọmọde to ni ipenija ara kaakiri ipinlẹ Kwara lasiko yii, koda, onitọhun ko nii kọsẹ rara.
Gomina AbdulRahman AbdulRazaq tipinlẹ naa lo lọ ba wọn ṣajọyọ ayẹyẹ ọdun tuntun lọjọ Ẹti, Fraide, ọjọ kẹta, oṣu Kinni, ọdun 2025.
Niṣe ni ayẹyẹ naa ti ileeṣẹ to n ri sọrọ idagbasoke araalu, iyẹn Social Development nipinlẹ naa ṣagbatẹru rẹ gbọna ara yọ, pẹlu bi Gomina AbdulRazaq ṣe ba gbogbo awọn ọmọ naa wọ aṣọ ẹgbẹjọda, to tun ba wọn f'ẹsẹ rajo.
Ile awọn ọmọ alailobii to wa niluu Ilorin, ipinlẹ Kwara ni eto ọhun ti waye pẹlu ilu, ijo ati ayọ loriṣiriṣi.
Nibẹ ni gomina tun ti ba wọn ge akara oyinbo lati fi ṣajọyọ ayẹyẹ ọdun tuntun naa .
Gomina AbdulRazaq ninu ọrọ rẹ, o ni awọn wa sibẹ lati ṣajọyọ pẹlu awọn ọmọ to ni ipenija ara, ati paapaa lati fun awọn olutọju wọn ni iwuri.
Kọmiṣanna Olaitan Abosede Buraimoh dupẹ lọwọ gomina ati ikọ akọwọrin rẹ fun asiko ti wọn fi silẹ lati yọju.
Buraimoh ni aridaju ni yiyọju gomina jẹ nipa fifi ifẹ han s'awọn ọmọde, paapaa awọn to ni ipenija ara.
No comments:
Post a Comment