Eyi gan-an laṣiri iku to pa gbajugbaja oniṣowo nni, Cash Madam - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, January 6, 2025

Eyi gan-an laṣiri iku to pa gbajugbaja oniṣowo nni, Cash Madam


Iroyin to tẹ wa lọwọ ti fidi rẹ mulẹ pe gbajugbaja oniṣowo nni, Oloye Arabinrin Khadijah Adebisi Edionseri tọpọ awọn eeyan mọ si Cash Madam ti jade laye.

Cash Madam lo jade laye lẹni ọdun mọkandinlaadọdun-un (89) lẹyin aisan rampẹ ti wọn loo niṣe pẹlu aisan ọjọ ogbo.

Ọjọ Aiku to kọja yii, ọjọ karun-un, oṣu Kinni, ọdun 2025 la gbọ pe mama naa ki ile aye pe o digboṣe.

Ọkan lara awọn ọmọ oloogbe, Ọmọwe Adebayo Adebowale lo fidi iroyin ọhun mulẹ, to si ni iku mama wọn kii ṣe ti ọfọ, bi ko ṣe pe amuwa Ọlọrun.

Ọmọwe Adebowale dupẹ lọwọ Ọlọrun lori igbe aye mama rẹ, to si lo ko ipa rere nigbesi aye ọpọ eeyan ko too jade laye.

Cash Madam ko too ku, ni Iya Sunnah ilu Ẹgba, Yewa ati ipinlẹ Ogun lapapọ.

“Pẹlu ẹmi imoore si Allah fun igbe aye rere to gbe, a n kede ipapoda mama wa, mama-mama, mama-mama-mama, Ọmọọbabinrin Kadijat Abike Adebisi Edionseri (née Elegbede), ẹni to pada sọdọ Adẹda rẹ lọjọ karun-un, oṣu Kinni, ọdun 2025 lẹni ọdun mọkandinlaadọrun, lẹyin aisan rampẹ,” Ọmọwe Adedayo sọ ninu atẹjade to fi sita.

Odu ni Cash Madam, kii ṣaimọ foloko nigba aye rẹ, ẹni to jẹ gbajugbaja ninu ka ṣe ẹṣọ ara, koda titi to fi jade laye.

Bo ṣe gbajumọ daadaa nipinlẹ Ogun to fi ṣebugbe, bẹẹ naa lo gbajumọ kaakiri Naijiria ati awọn agbegbe kan lagbaye.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI