Ọjọ buruku, eṣu gbomimu lọjọ Aje to kọja yii jẹ fun akọwe ijọba ipinlẹ Sokoto, Alaaji Muhammadu Bello Sifawa lori bo ṣe padanu ọmọ rẹ obinrin ati awọn ọmọ-ọmọ rẹ mẹta sinu ijamba ina.
Bo tilẹ jẹ pe titi di asiko ti a pari akojọpọ iroyin yii ni ko tii sẹni to le sọ pato ohun to ṣokunfa ijamba ina naa, ṣugbọn ti a gbọ pe ọkọ ọmọ rẹ nikan ni ori ko yọ ninu ijamba ọhun.
Obinrin oloogbe naa ni iyawo akọwe agba fun ileeṣẹ ijọba to n ri sọrọ ere idaraya ati idagbasoke awọn ọdọ nipinlẹ naa, Alaaji Muhammadu Yusuf Bello.
Oru ọganjọ, lasiko ti gbogbo eeyan ti sun lọ fọnfọn, la gbọ pe ina ọhun ṣẹyọ, to si jẹ pe nigba ti wọn yoo fi mọ nnkan to n ṣẹlẹ, aṣọ ko bọmọyẹ mọ.
Pẹlu agidi ni wọn sọ pe ọkọ obinrin naa fi rapala jade.
Irọlẹ ọjọ naa la gbọ pe wọn sinku awọn mẹrẹẹrin ni mọṣalaṣi Sheikh Shehu Usmanu Danfodiyo ti Sifawa to wa ni ile mọlẹbi baba oloogbe.
Gomina, igbakeji rẹ, ati gbogbo awọn alẹnulọrọ ninu ijọba, to fi mọ awọn afẹnifẹrẹ ni wọn ti ba akọwe ijọba naa kẹdun.
No comments:
Post a Comment