Awọn kansẹlọ bẹrẹ idanilẹkọọ ọlọjọ mẹrin ni Kwara - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Saturday, January 25, 2025

Awọn kansẹlọ bẹrẹ idanilẹkọọ ọlọjọ mẹrin ni Kwara


Ọjọ Ẹti to kọja yii ni ijọba ipinlẹ Kwara bẹrẹ eto idanilẹkọọ ọlọjọ mẹrin gbako fun gbogbo awọn aṣoju ijọba l'awọn ijọba ibilẹ mẹrindinlogun to sọ ipinlẹ Kwara papọ.

Eto idanilẹkọọ ọlọjọ ọhun, ti wọn pe akor rẹ ni "Strengthening Local Governance: Enhancing the Capacity of Local Government Legislative Council for Inclusive Development" ni wọn gbe kalẹ lati ro awọn kansẹlọ naa lagbara nipa ojuṣe wọn.

Ileeṣẹ to n eri seto ijọba ibilẹ, oye jijẹ ati idagbasoke agbegbe lo ṣagbatẹru eto naa, ni ajọṣepọ pẹlu ileeṣẹ FERHAT CONSULT LTD.

Nigba to n ṣiṣọ loju eto ọhun ni gbọngan ile itura Silver Gate, olori ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Kwara, Ọnarebu Yakubu Danladi Salihu rọ gbogbo awọn akopa lati farabalẹ daadaa, ki wọn le ri ọgbọn kọ.

Ọnarebu Salihu ti Ọnarebu Oba Magaji ṣoju fun, nigba to n sọrọ fi idunnu rẹ han wi pe idanilẹkọọ naa yoo tubọ ṣe agbelarugẹ ajọṣepọ laaarin ile igbimọ aṣofin ati ijọba ibilẹ naa

Nibẹ lo tun ti jẹ ko di mimọ pe idanilẹkọọ ọhun ti waye kọkọ waye, eyi ti wọn ṣagbekalẹ rẹ fawọn ọmọ ile igbimọ aṣofin, leyi to ti ṣe iranwọ pupọ ninu ajọṣepọ laarin wọn pẹlu ijọba.

Bakan naa lo gbe oriyin fawọn alẹnulọrọ nipa agbekalẹ eto idanilẹkọọ ọhun, to si loun nigbagbọ pe yoo jẹ ki wọn mọ ipo wọn ninu eto ijọba ibilẹ naa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI