Ẹgbẹ awọn gomina lorileede Naijiria ti sọ pe awọn ti bẹrẹ ifọwọsowọpọ pẹlu Aarẹ Bola Ahmed Tinubu lori ọrọ eto aabo ounjẹ, awọn iṣẹ idagbasoke ati awọn nnkan miran.
Alaga ẹgbẹ awọn gomina naa, AbdulRahman AbdulRazaq lo sọ eyi di mimọ laipẹ yii, lasiko abẹwo ti awọn aṣoju ẹgbẹ naa ṣe lọ sile Aarẹ Tinubu niluu Ekoo.
Nibẹ ni Gomina AbdulRazaq ti ṣalaye lẹkunrẹrẹ fun aarẹ nipa ibi ti ọrọ eto aabo lori ounjẹ, iṣẹ akanṣe idagbasoke, ati eto aabo ilu de duro lọdun 2024 to ṣẹṣẹ pari.
Ọjọru, ọsẹ yii, tii ṣe ọjọ kinni, oṣu Kinni, ọdun 2025 ni ẹgbẹ awọn gomina ọhun lo ki Aarẹ Tinubu ku ayẹyẹ ọdun tuntun.
Bakan naa ni Gomina AbdulRazaq tun sọ awọn ipa pataki to ti ko nipinlẹ Kwara, ati awọn iranwọ to n ṣe fun awọn gomina akẹgbẹ rẹ lati le jẹ ki awọn naa maa tẹsiwaju nipinlẹ wọn, ni ibamu pẹlu atunto ti aarẹ Tinubu n ṣe.
No comments:
Post a Comment