Awọn agbẹ ọlọọsin ẹja jẹ anfaani alaragbayida ni Kwara - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, January 23, 2025

Awọn agbẹ ọlọọsin ẹja jẹ anfaani alaragbayida ni Kwara


Oni, Ọjọbọ, ni awọn agbẹ ọlọọsin ẹja tun jẹ anfaani ọtun alaragbayida nipinlẹ Kwara pẹlu irolagbara ti ko lẹlẹgbẹ.

Ohun ti a gbọ ni pe gbogbo Ọjọbọ tii ṣe Tọside ni wọn yoo maa na ọja ti wọn ti n ta ẹja nipinlẹ Kwara, eyi ti wọn n pe ni “Thursday Fish Market.”

Ileeṣẹ to n ri seto agbẹ ati idagbasoke agbegbe igberiko ni wọn ṣagbatẹru eto naa, lati ṣe iranwọ fawọn agba ti wọn yan ọsin ẹja laayo.

Gbagede ọgba ileeṣẹ eto agbẹ ati idagbasoke agbegbe igberiko to wa niluu Ilorin ni ipatẹ ọja ẹja ọhun yoo ti maa waye, nibi ti awọn araalu yoo ti maa ra ẹja lowo pọọku.

Nigba to n sọrọ, Kọmiṣanna feto agbẹ, Arabinrin Oloruntoyosi Thomas ṣalaye pe eto ipatẹ ọja ẹja naa yoo fun araalu lanfaani lati ri ẹja oojọ bii ẹja aarọ, tilapia, croaker, at'awọn miran ra lowo pọọku lai laagun jinna.

O ni awọn ẹja naa ni wọn ti gba itọju to pe ye, leyi ti yoo ṣe agọ ara loore, dipo ko fun awọn eeyan ni aisan.



No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI