Ọna ara ọtọ ni eto ayẹyẹ ikẹkọọgboye gba yọ nile ẹkọ giga, fasiti ti iṣẹ agbẹ ati ọgbin lorileede Naijiria, eyi to wa niluu Abeokuta, Federal University of Agriculture (FUNAAB), pẹlu bi awọn ọjọgbọn mẹrindinlogoje ṣe fẹẹ kẹkọọ gboye lọsẹ yii.
Yatọ si awọn ọjọgbọn wọnyi, akẹkọọ to le diẹ ni ẹgbẹrun mẹta aabọ (3,567) ni wọn yoo kẹkọọ gboye lopin ọsẹ yii, ọjọ karundinlọgbọn, oṣu Kinni, ọdun 2025.
Bakan naa ni awọn 274 yoo kẹkọọ gboye Masters Degree.
Giwa agba ni fasiti naa, Ọjọgbọn Olusola Babatunde Kehinde to jẹ lo sọ eyi di mimọ lonii, Ọjọru, nibi ipade awọn akọroyin to waye ni gbọngan Red Chamber ti ile ẹkọ naa.
Ọjọgbọn Kehinde ṣalaye pe oriṣiriṣi aṣeyọri lawọn ti ṣe, leyi ti wọn yoo ṣafihan rẹ lasiko ayẹyẹ ikẹkọọgboye, ẹlẹẹkejilelọgbọn iru rẹ ti wọn bẹrẹ lọjọ Ẹti to kọja.
Nibẹ lo ti jẹ ko di mimọ pe lara awọn aṣeyọri naa ni bi ajọ to n ri sọrọ ilana eto ẹkọ nile ẹkọ giga lorileede Naijiria, NUC ṣe buwọlu awọn ilana eto ẹkọ tuntun fun wọn.
Ọjọgbọn Kehinde ni Kọlẹẹji mẹta ni wọn fi bẹrẹ nigba ti wọn da fasiti naa silẹ lọjọ Kinni, oṣu kinni, ọdun 1988, ṣugbọn to ni awọn Kọlẹẹji naa ti di mẹwaa bayii, ati pe wọn yoo tun di mọkanla ko to di pe ọdun 2025 dopin.
Giwa agba naa tẹsiwaju pe awọn gba iwe aṣẹ lati bẹrẹ ẹka ikẹkọọ tuntun mẹjọ, to si ni lara rẹ ni Library and Information Science; Cyber Security and Social Science; Software Engineering and Information Technology ati awọn miran.
"Bi mo ṣe n ba a yin sọrọ yii, mo layọ lati sọ fun un yin pe ilana eto ẹkọ mejidinlogoji (38 Academic Programmes) la n ṣe bayii, nigba ti a ni ẹka eto ẹkọ mẹrinlelaadọta (54, Departments), gbogbo wọnyi ni ajọ NUC buwọ lu fun wa," Ọjọgbọn Kehinde sọ eyi di mimọ.
"Akẹkọọ 3,567 ni wọn yoo kẹkọọ gboye lọjọ Satide, ọjọ karundinlọgbọn, oṣu yii. Ọgọfa ni awọn akẹkọọ to wa ni ipele akọkọ ti a mọ si First Class; awọn 1,626 ni wọn wa ni ipele Second Class Upper; 1,624 ni awọn to wa ni ipele Second Class Lower.
"Awọn akẹkọọ 164 ni wọn wa ni ipele Third Class, nigba ti awọn mẹtalelọgbọn wa ni ipele DVM.
"Mo tun fẹ jẹ ki ẹ mọ pe akẹkọọ ọgbọn ni wọn fẹẹ kẹkọọ gboye Post Graduate; awọn 274 ni wọn kẹkọọ gboye Masters Degree, nigba ti awọn 136 yoo gba iwe ẹri Ọjọgbọn," Giwa agba naa ṣalaye.
Bakan naa ni Ọjọgbọn Kehinde gbe oriyin fun gbogbo awọn alabaṣiṣẹpọ, igbimọ iṣakoso ile ẹkọ, to fi mọ awọn olukọ ati oṣiṣẹ, ati awọn akẹkọọ ti wọn n gbe iṣẹ wọn yọ.
"A ko le ṣe awọn aṣeyọri yii lai si awọn oṣiṣẹ to fi ara jin fun iṣẹ isin ile ẹkọ yii, ati awọn akẹkọọ wa ti wọn n fi iwa ọmọluabi han ni gbogbo igba," Ọjọgbọn Kehinde sọrọ
Bakan naa ni Ọjọgbọn Kehinde jẹ ko di mimọ pe "ọdun kẹta ree ti awọn ti ni eto ẹkọ ti ko dakudaji, bakan naa ni ọdun yii yoo jẹ ọdun kẹrin ti a ma maa ṣe ayẹyẹ ikẹkọọgboye lai dawọ duro. Eyi ko le ṣee ṣe lai si ifọwọsowọpọ awọn oṣiṣẹ ati akẹkọọ."
No comments:
Post a Comment