Anfaani iṣẹ tuntun ree fawọn araalu ni Kwara - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Sunday, January 19, 2025

Anfaani iṣẹ tuntun ree fawọn araalu ni Kwara


Lati ṣagbelarugẹ fun eto imọtoto ayika ati agbegbe, ijọba ipinlẹ Kwara ti kede pe aaye ti ṣi silẹ fawọn ileeṣẹ aladani ti wọn mọ nipa ilẹ didanu.

Ijọba ni awọn ileeṣẹ ti wọn dantọ nipa itọju ayika ati agbegbe, ki eto imọtoto le tubọ kẹsẹjare lawọn n wa lati tọwọ bọwe adehun pẹlu.

Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, ileeṣẹ to n mojuto eto ayika lo gbe ikede ọhun sita.

Wọn ni awọn ileeṣẹ to ba yọju ni wọn yoo ba dowo pọ, ti wọn yoo si sọ awọn agbegbe ti wọn ma maa ṣiṣẹ.

Awọn agbegbe naa ni wọn yoo ti maa gba ilẹ idọti, lati lọ da a nu s'awọn agbegbe ti ijọba buwọlu.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI