Alaga ijọba ibilẹ ni Kano yan alabaṣiṣẹpọ ọgọta - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, January 7, 2025

Alaga ijọba ibilẹ ni Kano yan alabaṣiṣẹpọ ọgọta


Alaga ijọba ibilẹ Nasarawa to wa nipinlẹ Kano, Yusuf Imam ti kede yiyan awọn alabaṣiṣẹpọ ti ko din ni ọgọta fun iṣakoso rẹ.

Yusuf Imam tọpọ awọn eeyan mọ si Ogan Boye lo kede yiyan awọn eeyan naa, to si ni wọn yoo ṣiṣẹ papọ ni oriṣiriṣi ẹka iṣakoso rẹ gẹgẹ bi alaga.

Ninu atẹjade ti akọwe ijọba ibilẹ naa, Ado Muhd Hotoro fi sita, o ni iyansipo naa wa lara igbiyanju alaga lati ṣe agbelarugẹ fun idagbasoke ijọba ibilẹ naa.

Atẹjade ọhun to buwọ lu lọjọ kẹfa, oṣu Kinni, ọdun 2025, Hotoro sọ pe kaakiri ẹka iṣẹ ni awọn alabaṣiṣẹpọ ọhun yoo ti ṣiṣẹ.

Lara wọn naa ni akọroyin mejidinlogun ti yoo maa ṣiṣẹ pọ pẹlu oniruuru ẹka iṣejọba kaakiri ijọba ibilẹ naa, to fi mọ awọn ileewosan alabọde.

Atẹjade ati orukọ awọn alabaṣiṣẹpọ naa ree:




No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI