Adron Homes gbe asia aami idanimọ tuntun jade lara ọtọ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, January 7, 2025

Adron Homes gbe asia aami idanimọ tuntun jade lara ọtọ


...wọn tun sọ erongba wọn fun agbaye sita

Ọjọ manigbagbe ni ọjọ Aje, ọjọ keje, oṣu Kinni, ọdun 2025 tun jẹ ninu itan nileeṣẹ Adron Homes and Properties Limited, gbajugbaja ileeṣẹ to n ta ilẹ ati dukia lorileede Naijiria.

Asia idanimọ ti a mọ si ‘Logo’ tuntun ni wọn ṣafihan rẹ fun gbogbo ọmọ Naijiria, paapaa agbaye lapapọ.

Igba akọkọ ree ti ileeṣẹ Adron Homes yoo maa ṣe ayipada ọtun si asia idanimọ wọn naa latigba ti wọn ti bẹrẹ lọdun mejila sẹyin, gẹgẹ bi a ṣe gbọ.

Olu-ileeṣẹ Adron Homes to wa nipinlẹ Eko ni eto ọhun ti waye, nibi ti ọpọ awọn alẹnulọrọ nileeṣẹ naa kaakiri Naijiria ti peju lati ṣajọyọ.

Eto ara-ọtọ naa ti wọn ṣe lo jẹ eyi to ni ipa pataki latigba ti wọn ti n mu ayipada rere ati idagbasoke ba eto ile gbigbe lorileede Naijiria.

Asia idanimọ tuntun naa yatọ gedengbe si eyi ti wọn n lo tẹlẹ, ti wọn si ṣe lara-ọtọ ti ko wọpọ lawujọ.

Asia naa ṣafihan apele wọn, eyi to sọ pe ‘building cities, communities, and homes’, iyẹn ni pe gbigbe ilu, agbegbe ati ile dide.

Ninu asia idanimọ tuntun naa ni wọn ti ṣafihan aami apele wọn ti wọn fi n ṣagbelarugẹ ba ile kikọ lorileede Naijiria ati ilẹ Afrika lapapọ.

Nigba to n sọrọ lori erongba si idagbasoke naa, alaṣẹ ati oludasilẹ ileeṣẹ Adron Homes, Aare Adetola Emmanuelking, ṣalaye pe wọn kii kan-an ṣe asia idanimọ lasan, bi ko ṣe wọn duro gẹgẹ bii asọtẹlẹ fun ọjọ iwaju.

“Asia idanimọ wa jẹ eyi to n sọ nipa ohun ti a jẹ, ibi ti a n lọ gẹgẹ bi ileeṣẹ. Asiko ti to lati gbe ileeṣẹ Adron Homes lọ si agbaye, ati agbaye wa si ileeṣẹ Adron Homes,” Aarẹ EmmanuelKing jẹ ko di mimọ.

Alakoso naa ni ko si nnkan meji to gbe awọn duro lati ọdun 2012 titi di asiko yii, to kọja oore ọfẹ nla Ọlọrun, to si ni awọn n ṣamulo oore ọfẹ naa bo ti tọ ati bo ti yẹ.

Bakan naa lo jẹ ko di mimọ pe awọn tun n bẹrẹ agbekalẹ lati mu eto ile gbigbe kaakiri agbaye dide lara-ọtọ, fun gbogbo eeyan lati di onile lori lai daamu.









No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI