AbdulRazaq bu ọla fun iyawo Aarẹ Tinubu, Olurẹmi ati awọn miran ni Kwara - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, January 27, 2025

AbdulRazaq bu ọla fun iyawo Aarẹ Tinubu, Olurẹmi ati awọn miran ni Kwara


Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti ipinlẹ Kwara ti yi awọn orukọ dukia ijọba kọọkan pada, lati fi bu ọla fun awọn alẹnulọrọ ni Naijiria.

Lara wọn ni iyawo aarẹ Naijiria, Sẹnetọ Olurẹmi Tinubu; Gomina tẹlẹ; Bamigboye, Innih, Lawal, Ọmọwe Amuda Aluko, Ndalolo, Rashidi Yekini, to fi mọ awọn miran 

Awọn akanṣe iṣẹ ti gomina naa dawọ le, lo yi awọn orukọ wọn pada, lati fi bu ọla fawọn to n ko ipa ribiribi ninu idagbasoke ilẹ Naijiria.

Ile iwosan ijọba ti Civil Service Clinic, eyi ti Gomina AbdulRazaq ṣẹṣẹ pari, lo sọ lorukọ Sẹnetọ Oluremi Tinubu, eyi ti wọn yoo fi lọlẹ lọjọ Iṣẹgun, ọsẹ yii.

Aarin ọjọ kejidinlọgbọn si ọgbọn ọjọ, oṣu Kinni ọdun yii ni wọn yoo fi ṣe ifilọlẹ awọn akanṣe iṣẹ ọhun.

Bakan naa ni iyawo aarẹ yoo tun maa lewaju lati ṣe ifilọlẹ awọn akanṣe iṣẹ naa bii gbọngan imọ ẹrọ igbalode (ICT) to wa ninu ọgba fasiti ipinlẹ Kwara, afara Unity, ICU, afara Tunde Idiagbon.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI