Aarẹ EmmanuelKing, alaṣẹ Adron Homes kẹdun iku Onanuga, Ọnarebu to ku n'Ikẹnnẹ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, January 17, 2025

Aarẹ EmmanuelKing, alaṣẹ Adron Homes kẹdun iku Onanuga, Ọnarebu to ku n'Ikẹnnẹ


Aare Adetola Emmanuelking, alaṣẹ ati oludasilẹ ileeṣẹ Adron Group ti kẹdun iku Oloogbe, Ọnarebu Adewunmi Oriyomi Onanuga.

Ọnarebu Adewunmi tọpọ awọn eeyan mọ si Ijaya lo doloogbe laipẹ yii, lẹyin aisan rampẹ.

Oloogbe naa to jẹ the Yeye Ọba ilu Makun lo n ṣoju ẹkun Ikenne, Sagamu ati Remo nile igbimọ aṣoju-ṣofin l'Abuja.

Nigba to n ṣapejuwe oloogbe naa, Aarẹ EmmanuelKing sọ pe adari rere to n lewaju idajọ ododo, to si n ro awọn obinrin lagbara ni.

Aarẹ EmmanuelKing ni ohinrin naa kii ṣe ẹni ti wọn le tete gbagbe, nitori awọn ipa rere to ti ko lawujọ, paapaa bo ṣe ara jin fun iṣẹ isin ilu.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI