A ko tii fi oju opo iforukọsilẹ igbanisiṣẹ TESCOM sita - Alaga - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, January 22, 2025

A ko tii fi oju opo iforukọsilẹ igbanisiṣẹ TESCOM sita - Alaga


Ajọ to n ri sọrọ eto ẹkọ, Teaching Service Commission, TESCOM, ẹka tipinlẹ Kwara ti sọ pe awọn ko tii fi oju opo iforukọsilẹ igbanisiṣẹ sita lasiko yii.

Ninu atẹjade ti Sam Bola Onile to jẹ akọwe iroyin ajọ naa fi sita, o ni ayederu pọmbele ni itakun ayelujara ti awọn onijibiti fi sita.

Onile sọ pe awọn alagabagebe ni wọn wa nidi itakun naa lati ṣi awọn araalu lọkan.

Bakan naa lo jẹ ko di mimọ pe ajọ naa yoo fi itakun ayelujara ti awọn eeyan yoo ti forukọ silẹ sita laipẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI