A ko nii dẹkun lati maa ṣe iranlọwọ ironilagbara fawọn ọdọ - Ijọba Kwara - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, January 16, 2025

A ko nii dẹkun lati maa ṣe iranlọwọ ironilagbara fawọn ọdọ - Ijọba Kwara


Ijọba ipinlẹ Kwara tun ti sọ pe ko si ohun to le mu wọn dawọ duro lati maa ṣe iranlọwọ ironilagbara fun gbogbo awọn ọdọ patapata.

Ọmowe Abdulwasiu Olayinka Tejidini to jẹ alakoso agba fun ileeṣẹ Kwara State Social Investment Programme (KWASSIP) lo fidi rẹ mulẹ laipẹ yii niluu Ilorin.

Tejidini sọ pe igbayegbadun ati ilọsiwaju awọn ọdọ nipa dida okoowo silẹ fun agbelarugẹ eto ọrọ aje wọn.

Siwaju sii lo ni gbogbo awọn ọdọ ni yoo jẹ anfaani eto iranwọ nipa dida okoowo keekeke silẹ, ati fun awọn akanda to ni ipenija ara.

Nibi ipade awọn akọroyin naa to waye ninu gbọngan ipade ileeṣẹ to n ri seto iṣuna niluu Ilorin, Ọmọwe Tejidini ṣalaye pe ọpọ awọn eeyan ni wọn ti jẹ anfaani owo loriṣiriṣi.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI