Alakoso agba ati oludasilẹ ijọ Ori Oke Ina ati Iṣẹ Iyanu (Mountain of Fire and Miracles Ministries) kaakiri agbaye, Ọmọwe Daniel Kolawole Olukọya ti sọ asọtẹlẹ ibẹru fun gbogbo awọn ọkunrin oloju-komu-o-lọ, to si ṣe ikilọ fun wọn lati jawọ.
Ọmọwe Olukoya lo sọ asọtẹlẹ naa lasiko to n ba awọn ọmọ ijọ rẹ ati awọn akopa nibi aṣalẹ aisun ọdun to waye kọja lọ yii sọrọ.
Nibẹ lo ti ni ọdun 2025 jẹ ọdun to nilo ọpọlọpọ adura gidigidi fun oniruuru igbekun lati ja.
Bakan naa ni Ọmọwe Olukoya tun sọ pe ọdun 2025 ni Ọlọrun yoo tu aṣiri ọpọ awọn ayederu Wolii ti wọn n fi orukọ Ọlọrun lu jibiti.
Ẹkunrẹrẹ asọtẹlẹ naa ree:
2025 yoo jẹ ọdun awọn ogun ajoji
Awọn ti ko ni ogo yoo ja fitafita lati ba ogo awọn to ni ogo jẹ
Awọn agba ofifo yoo fẹẹ ba ti awọn ti agba wọn kun jẹ
Awọn ti ko ri aanu gba yoo fẹẹ ba ti awọn to rii anu gba jẹ
Awọn ti irawọ wọn ko tan daadaa yoo gbiyanju lati ja awọn irawọ to n tan lulẹ
Awọn ọkunrin ti ko ni imulẹ yoo gbiyanju lati ja awọn ọkunrin to ni imulẹ lulẹ
Awọn ti ko ni ikọla yoo gbiyanju lati pa awọn to ni ikọla
Awọn to wa ninu ide yoo maa ba awọn to ni ominira ja
Iru yoo maa ba ori ja
Awọn ti ko ni afojusun yoo maa ba awọn to ni afojusun ja
Awọn oniwa agabagebe yoo gbiyanju lati pa awọn olotitọ
Awọn ole yoo maa ba awọn oni nnkan ja
2025 jẹ ọdun ti wọn yoo fẹẹ da ibukun atokewa duro
Yoo jẹ ọdun ti wọn yoo gbe Joseph, Esther ati Daniel dide, ti Ọlọrun yoo gbe awọn adari ti yoo ṣe atunṣe dide
O jẹ ọdun ti aile gbadura lewu gidi
O jẹ ọdun ti a nilo adura lati gbogun ti iji lile ti ọrọ aje ati oṣelu
O tun jẹ ọdun ti a nilo adura lati gbogun ti oniruuru iji bii omiyale ati oriṣiriṣi afẹfẹ idaamu
Ọdun ti a nilo lati gbadura lodi si ailera
O jẹ ọdun imuoadabọsipo awọn anfaanu fun ọpọlọpọ
O jẹ ọdun itusilẹ ti ko lopin
O jẹ ọdun awọn iyipada ajoji
O jẹ ọdun ti Ọlọrun yoo ja awọn ayederu ojiṣẹ Ọlọrun sihoho
O jẹ ọdun ajalu fun awọn baale ile ti wọn fẹran lati maa jade pẹlu awọn obinrin ajoji.
Awọn ojiṣe lati isalẹ omi ti ran awọn obinrin wọn sita lati ba ọpọ ọkunrin laye jẹ.
Ọpọ ilẹkun ni yoo ṣi silẹ fun awọn to n wo oju Ọlọrun fun igbeyawo ati eso ti inu
O jẹ ọdun to jẹ pe ti ẹ ba kọ lati dariji ara yin, o maa so eso rere pupọ.
No comments:
Post a Comment