Yiyọ owo iranwọ ori epo kii ṣe lati fiya jẹ araalu – Tinubu pariwo sita - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Sunday, December 1, 2024

Yiyọ owo iranwọ ori epo kii ṣe lati fiya jẹ araalu – Tinubu pariwo sita


Aarẹ Naijiria, Bọla Ahmẹd Tinubu ti sọrọ jade nipa idi ti iṣakoso rẹ fi yọ owo iranwọ ori epo rọbii, to si ni kii ṣe lati fi ni araalu lara, bi ko ṣe lati fi gba orileede na silẹ kuro loko iparun.

Aarẹ Tinubu jẹ ko di mimọ pe o ṣee ṣe ki eto ọrọ aje Naijiria ti dẹnukọlẹ kọja sisọ bi iṣakoso oun ko ba kede yiyọ owo iranwọ ori epo naa kuro lọjọ ibura gẹgẹ bi aarẹ.

Bi ẹ ko ba gbagbe, ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu karun-un, ọdun 2023 ni aarẹ kede yiyọ owo naa kuro, ṣugbọn ti ijọba apapọ ti wa sọ pe igbesẹ naa ti n so eso rere fun orileede naa.

Aarẹ Tinubu sọrọ yii nigba to n sọrọ nibi eto ayẹyẹ ikẹkọọ gboye fasiti FUTA, ẹlẹẹkẹrinlelọgbọn ati ikarundinogoji iru rẹ to waye lopin ọsẹ to kọja.

Ọjọgbọn Wahab Ẹgbẹwọle to ṣoju aarẹ sọ pe kii ṣe pe oun ko mọ nipa iya to n jẹ araalu, ṣugbọn to ni lẹyin okunkun, imọlẹ nla yoo tan.

Ninu ọrọ rẹ, o sọ pe “Gẹgẹ bi ẹ ti ṣe mọ, a gba iṣakoso lasiko ti agbami gbese fẹẹ gbe orileede yii lọ nipa owo iranwọ ori epo rọbii ati owo dọla. Iranwọ naa ni lati fi mu igbe aye rọrun fawọn otoṣi ati gbogbo awọn ọmọ Naijiria.

“Gbogbo wa la mọ pe otitọ daju pe awọn otoṣi ati alaini Naijiria ni wọn n jiya awọn ohun to yẹ ka maa fi ṣe iranlọwọ fun wọn lati maa gbe igbe aye rere. Ṣugbọn o ṣeni laanu wi pe igbe aye rere tia lero wi pe a n gbe, ayederu ni, eyi to le mu orileede yii lọ soko iparun ayafi bi a ba tete gbe igbesẹ akikanju to yẹ.

“O ṣe pataki lati daabo bo ọjọ ọla awọn ọmọ wa nipa gbigbe igbesẹ to ṣe pataki lati yọ owo iranwọ ori epo ati atunṣe si paṣipaarọ owo. Kii ṣe pe nko mọ ipalara ti yoo ko ninu igbe aye awọn eeyan wa.”

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI