Wọn sinku Mahe, olori oṣiṣẹ gomina ipinlẹ Kwara pẹlu ibanujẹ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Sunday, December 29, 2024

Wọn sinku Mahe, olori oṣiṣẹ gomina ipinlẹ Kwara pẹlu ibanujẹ


Bi ẹlẹkun ṣe n sunkun, bẹẹ l'awọn eeyan n gbera ṣanlẹ nibi eto isinku olori awọn oṣiṣẹ Gomina AbdulRahman AbdulRazaq tipinlẹ Kwara, Oloogbe Abdulkadir Mahe to doloogbd lojiji.

Irọlẹ ọjọ Abamẹta to kọja yii ni wọn sinku oloogbe naa to jẹ laye laarọ ọjọ Abamẹta.

Ẹsẹ ko gbero nibi eto isinku naa, lara wọn si ni Gomina Abdulrahman Abdulrazaq tipinlẹ Kwara; Gomina Ahmed Usman Ododo tipinlẹ Kogi; awọn ọga agba l'ẹnu iṣẹ ijọba, mọlẹbi, ọrẹ ati alabakẹdun.

Nibi eto isinku naa ti Imaamu agba niluu Ilorin, Sheikh Muhammad Bashir Soliu dari rẹ, ni Gomina AbdulRazaq ti sọ pe olufọkansin ni oloogbe naa, to si farajin fun iṣẹ ilu.










No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI