Wọn jawe oye le Ọba Adebowale, Elerin tiluu Erin-Ile lori - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, December 24, 2024

Wọn jawe oye le Ọba Adebowale, Elerin tiluu Erin-Ile lori


Ẹsẹ ko gbero niluu Erin-Ile to wa nipinlẹ Kwara lọjọi Aje to kọja yii nibi ti wọn ti jawe oye le Ọba Jimoh Adesoye Adebowale Adetona akọkọ lori.

Igba ọtun lo wọnu ilu naa, pẹlu bi onile, alejo ati awọn afẹnifẹre lapapọ ṣe lọ ba kabiyesi naa yọ nigba ti wọn jawe oye lee lori.

Igbimọ awọn afọbajẹ niluu Erin-Ile ti Esaa, Oloye Abdulateef Buhari lewaju wọn gba ọba tuntun naa lamọran lati fi ifẹ baraalu lo, ati pe ko mu ki iṣọkan jọba siwaju sii.

Nigba toun naa n sọrọ, Ọba Adebowale sọ pe oun yoo gbajumọ eto iṣẹ fawọn ọdọ, ati pe gbogbo ọdọ ni wọn gbọdọ ni iṣẹ lọwọ.

O lasiko lati mu idagbasoke ati ilọsiwaju ba eto ọrọ aje naa ti de, nitori pe gbogbo iriri toun gbe wa lati ilẹ Amẹrika loun yoo lo lati fi ṣiṣẹ.

Fọto:

















No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI