Awọn ọmọ Naijiria ni wọn n lewaju ninu akọsilẹ orukọ awọn ti awọn eeyan sọrọ wọn julọ lọdun 2024, eyi ti ajọ Top Charts Africa gbe jade.
Ipo mejidinlogun ni awọn ọmọ Naijiria di mu ninu akọsilẹ ọgbọn ti TCA gbe jade soju opo wọn laipẹ yii.
Gbajugbaja onkọrin takasufee nni, Wizkid lo n lewaju ninu orukọ naa.
Wizkid lawọn eeyan n sọrọ rẹ julọ lasiko toun pẹlu akẹgbẹ rẹ, Davido kọlu ara wọn, ati orin rẹ tuntun ‘Morayo’ to gbe jade laipẹ yii.
Aarẹ William Ruto ti orileede Kenya lo wa ni ipo keji lori tabili naa.
Inu oṣu Kẹfa ni Ruto gba oju ọpọ awọn iwe iroyin nigba ti ogunlọgọ awọn ọmọ ilẹ Kenya dide lati fẹhonu han lori ẹkunwo owo ori ti awọn aṣofin buwọ lu.
Lẹyin ifẹhonu han tawọn eeyan ṣe lọ sile igbimọ aṣofin ilẹ naa, Aarẹ William Ruto la gbọ pe o tako ofin naa ti wọn ti buwọ lu, eyi ti wọn pe ni “Appropriations Bill 2024”.
Davido lo wa ni ipo kẹta. Ariwo Davido pẹ nita pẹlu bi ti ayẹyẹ igbeyawo rẹ pẹlu Chioma tun ṣe wọle loṣu Kẹfa, eyi ti wọn pe ni ‘Chivido 2024.’
Aarẹ ilẹ Naijiria, Bola Ahmed Tinubu; Alaṣẹ ileeṣẹ Dangote Group, Aliko Dangote; Olootu ijọba ilẹ Kenya tẹlẹ, Raila Odinga; Bobrisky; onkọrin ilẹ South Africa, Tyla; oloṣelu Naijiria nni, Peter Obi, ati Liema Pantsi to jẹ onkọrin ilẹ South Africa lo wa ni ipo kẹrin si ipo kẹwaa.
Baltasar Engonga, ọkunrin ti wọn lo ba irinwo obinrin laṣepọ nilẹ Equatoria Guinea naa ko gbẹyin ninu akọsilẹ naa.
Ẹkunrẹrẹ akọsilẹ naa ree:
1. Wizkid
2. President William Ruto
3. Davido
4. President Bola Ahmed Tinubu
5. Aliko Dangote
6. Raila Odinga
7. Bobrisky
8. Tyla
9. Peter Obi
10. Liema Pantsi
11. Rema
12. Rigathi Gachagua
13. Khosi Twala
14. Former President Uhuru Kenyatta
15. Ademola Lookman
16. Asake
17. Very Dark Man
18. Drill
19. Nyesom Wike
20. President Cyril Ramaphosa
21. Reno Omokri
22. Rose Owusu Konadu
23. Victor Osimhen
24. Baltasar Engonga
25. Sharon Ooja
26. Toyin Abraham
27. Babu Owino Paul
28. Chidimma Vanessa Adetshina
29. Danny Walter
30. Pastor Enoch Adeboye
No comments:
Post a Comment