Wahala de bawọn to n kọti ikun seto imọtoto ni Kwara, ijọba ṣetan lati fiya nla jẹ wọn - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Sunday, December 1, 2024

Wahala de bawọn to n kọti ikun seto imọtoto ni Kwara, ijọba ṣetan lati fiya nla jẹ wọn


Ijọba ipinlẹ Kwara ti sọ pe gbogbo awọn to n kọti ikun sọrọe to imọtoto nipinlẹ yoo bẹrẹ sii foju winna ofin, nitori pe awọn ko tii maa fọwọ ra wọn lori mọ.

Ijọba sọ pe gbogbo awọn to ba kọ jalẹ lati kopa ninu eto gbale-gbata to n waye ni gbogbo Satide to gbẹyin ninu oṣu ni wọn yoo bẹrẹ sii jẹ iyan wọn niṣe bayii.

Kọmiṣanna feto ayika nipinlẹ Kwara, Nafisat Buge lo ṣe ikilọ yii nibi eto gbale-gbata oloṣooṣu to waye niluu Ilọrin lopin ọsẹ to kọja yii, iyẹn to gbẹyin ninu oṣu kọkanla, ọdun 2024.

Ninu atẹjade ti akọwe iroyin ileeṣẹ naa, Kamaldeen Aliagan fi sita, Buge jẹ ko di mimọ pe awọn eeyan ti ko din ni aadọjọ (150) lọwọ palaba wọn ti segi lori aimu eto imọtoto lọkunkundun nipinlẹ Kwara.

O ni awọn wọnyi si ni wọn ti foju ba ile-ẹjọ alagbeeka kaakiri ipinlẹ Kwara, ti wọn si ti gba idajọ bo ti tọ ati bo ti yẹ.

Kọmiṣanna ọhun fi kun ọrọ rẹ pe pẹlu oriṣiriṣi eto ti ijọba ti ṣe lati da awọn eeyan lẹkọ nipa pataki eto imọtoto lawujọ, paapaa ninu awọn iwe iroyin ati lawọn oju opo ayelujara, sibẹ o ni iyalẹnu lo jẹ wi pe awọn araalu ṣi n tapa si ofin eto imọtoto layika wọn.

O ni o n jẹ kayeefi wi pe awọn ọlọkada, oni kẹkẹ maruwa ati awọn ọlọja ni wọn n ṣiṣẹ lasiko to yẹ ki wọn mu eto imọtoto lọkunkundun, eyi to to sọ pe ko bojumu to.

“Gbogbo igba la n ṣe ipolongo lati maa fi ṣe idanilẹkọọ fawọn eeyan nipa ọjọ imọtoto ati awọn ohun to yẹ ki wọn ṣe laarọ kutu ọjọ Satide to gbẹyin ninu oṣu, sibẹ awọn eeyan ṣi n lọ kaakiri lati maa ṣiṣẹ oojọ wọn.

“Eyi ko jẹ itẹwọgba rara. Awọn to ba ti tapa si ilana yii yoo bẹrẹ sii foju winna ofin”

Bakan naa lo fọkan awọn araalu balẹ wi pe iṣakoso wọn ko nii dawọ duro ninu igbiyanju rẹ lati maa ṣeto imọtoto ayika ati agbegbe, ki awọn eeyan le maa gbe ninu ilera pipe ni Kwara.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI