Gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu ti kede pe ijọba ipinlẹ naa ti ṣetan lati ṣi awọn akanṣe iṣẹ alaragbayida.
Ọjọ Aje, ọsẹ to n bọ ni gomina sọ pe oun yoo ṣi opopona tuntun mẹrindinlogoji, afara marun-un ati arara ẹlẹsẹ kan ti wọn ṣẹṣẹ pari fun lilo araalu.
Oludamọran oataki fun gomina lori ọrọ nipa akanṣe iṣẹ idagbasoke, Onimọ-ẹrọ Olufẹmi Daramọla lo jẹ ko di mimọ lọjọ Ẹti, oni, lasiko to n b'awọn akọroyin sọrọ gbọngan Bagauda Kaltho Press Centre, Alausa, Ikẹja.
Onimọ-ẹrọ Daramọla sọ pe aṣeyọri nla to jọju ni awọn akanṣe iṣẹ naa ti iṣakoso Gomina Sanwo-Olu fi ara jin fun.
Siwaju lo jẹ ko di mimọ pe awọn opopona tuntun yii yoo mu adinku ba sunkẹrẹ-fakẹrẹ ọkọ laarin ilu.
O tẹsiwaju pe ijọba ibilẹ Agege, Alimosho, Badagry, Eti-Osa, Ikeja, ati Kosofe, ni awọn iṣẹ akanṣe ọhun wa.
Bakan naa lo ni atunṣe opopona Dọpẹmu to wa ni Agege, ṣiṣe opopona tuntun Abiola si Onijemo pẹlu afara Ifako-Ijaiye; atunṣe opopona Irede ni Amuwo Odofin, ati atunṣe opopona Oyinkan Abayomi Drive ni Ikoyi, Eti-Osa, ati awọn miran.
No comments:
Post a Comment