Sanwo-Olu buwọ lu ofin ina mọnamọna l’Ekoo - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, December 4, 2024

Sanwo-Olu buwọ lu ofin ina mọnamọna l’Ekoo


Orin ọpẹ lawọn ọmọ ati olugbe ipinlẹ Eko mu sẹnu lọjọ Iṣẹgun, ọsẹ yii nigba ti Gomina Babajide Sanwo-Olu buwọ lu iwe ofin ina mọnamọna fun ipinlẹ naa.

Nini eto ibuwọlu naa ni Gomina Sanwo-Olu ti jẹ ko di mimọ pe gbogbo awọn olugbe ipinlẹ Eko ni yoo maa jẹ mudunmudun ina mọnamọna lai ṣẹju, eyi to ja geere ju ti atẹyinwa lọ.

Ileeṣẹ Gomina to wa ni Alausa, Ikẹja nipinlẹ naa ni eto ibuwọlu naa ti waye, nibi ti awọn bii igbakeji gomina, Kadri Hamzat, awọn ọmọ ile igbimọ aṣofin, to si mọ awọn alẹnulọrọ ninu ijọba Eko ti peju.

Nibẹ ni Gomina Sanwo-Olu ti gbe oriyin fun ile igbimọ aṣofin ipinlẹ naa lori bi wọn ṣe gbe iwe aba ofin naa dide, ti wọn si buwọ lu lati mu ayipada ati ilọsiwaju rere ba eto ọrọ aje.

O ni igbesẹ naa yoo mu ayipada rere ba araalu Eko nipa eto ọrọ aje.

Bakan naa lo tun jẹ ko di mimọ pe, bo tilẹ jẹ pe iwe aba ofin naa ti wa nilẹ lati ọdun diẹ sẹyin, sibẹ awọn ni lati buwọ lu u fun idagbasoke ati itẹsiwaju nipa ina mọnamọna ti mu imugbooro ba eto ọrọ aje Eko.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI