Ile igbimọ aṣofin agba lorileede Naijiria ti paṣẹ pe ki wọn lọ gbe awọn alakoso ileeṣẹ to n ṣe opopona nni, Julius Berger lori awọn ẹsun ti wọn fi kan wọn.
Awọn alakoso Julius Berger ọhun la gbọ pe wọn kọ lati yọju sile igbimọ aṣofin, lati dahun awọn ibeere lori ẹsun ti wọn fi kan wọn, lori bi wọn ṣe pa ọpọ iṣẹ akanṣe ti kaakiri ilẹ Naijiria, ti wọn ko si ṣe wọn.
Ọjọbọ, oni ni ile igbimọ aṣofin agba fẹnuko nibi ijokoo wọn, lẹyin ti Sẹnetọ Osita Ngwu to n ṣoju agbegbe Enugu West gbe ẹnu le ọrọ naa niwaju igbimọ to n ri sọrọ iṣẹ ode.
A gbọ pe ọpọ igba ni ile igbimọ aṣofin ti kọwe ranṣẹ sawọn alakoso ileeṣẹ Julius Berger lati wa ṣalaye idi ti wọn fi pa awọn akanṣe iṣẹ opopona to wa nikawọ wọn ti, ṣugbọon ti wọn ko yọju lati ṣalaye ohun to ṣẹlẹ.
Sẹnetọ Ngwu sọ pe o ṣe pataki lati mọ ohun to fa idaduro awọn opopona to wa kaakiri Naijiria.
Ngwu sọ pe gẹgẹ bi ofin ati ilana ile igbimọ naa, awọ nilo lati kọwe aṣẹ lati lọ fi kele ofin gbe ẹnikẹni to ba tapa si aṣẹ lati yọju si wọn, lẹyin ti wọn ba fi iwe pe wọn, ṣugbọn ti wọn kọ jalẹ.
“Bi igbimọ ba ranṣẹ pe ẹnikẹni tabi ẹda kan lati yọju, ti ẹni naa ko si ran aṣoju tabi pe ko yọju funra rẹ, ohun to kan ni lati gbe iwe aṣẹ fifi kele ofin gbe iru ẹni bẹẹ.”
No comments:
Post a Comment