Oriire nla: Awọn agbẹ ọlọọsin ẹja bọ saye ni Kwara - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, December 3, 2024

Oriire nla: Awọn agbẹ ọlọọsin ẹja bọ saye ni Kwara


Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti ipinlẹ Kwara ti ṣeleri wi pe iṣakoso oun yoo tubọ maa ṣe iranwọ to jọju fun gbogbo awọn agbẹ, paapaa awọn agbẹ ọlọọsin ẹja.

AbdulRazaq ni awọn irinṣẹ igbalode ti yoo mu ki iṣẹ ọsin ẹja ati bi wọn yoo ṣe maa sọ awọn ẹyin ẹja di ọmọ ẹja loun yoo pese fun gbogbo awọn agbẹ to mu iṣẹ naa lọkunkundun.

Gomina ṣeleri yii lati fi saami ayẹyẹ ọjọ ẹja lagbaye, iyẹn World Fisheries Day, eyi ti ipinlẹ Kwara ko gbẹyin ninu awọn ilu to n ṣayẹyẹ naa lagbaye.

Siwaju sii lo ni Kwara wa lara awọn ipinlẹ to n ṣoowo ẹja aarọ julọ ni Naijiria, to si ni ijọba ko nii dawọ duro lati maa ṣe iranwọ ti yoo jẹ ki wọn ṣi ma duro ṣinṣin.

AbdulRazaq sọrọ yii nibi ayẹyẹ ayajọ ẹja lagbaye, eyi ti ileeṣẹ to n sọrọ iṣẹ agbẹ ti ọgbin nipinlẹ naa ṣagbekalẹ rẹ, eyi ti wọn pe akori tọdun yii ni “The Economic Significance of Fishery to the Development of Kwara State”.

Gomina ti Kọmiṣanna fẹtọ agbẹ ati ọgbin, Arabinrin Ọlọruntoyọsi Thomas ṣoju fun jẹ ko di mimọ pe gbogbo ipenija to n dojukọ ẹka iṣẹ agbẹ, paapaa ọsin ẹja lawọn yoo fopin si nipinlẹ naa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI