Ọpọ awọn ojiṣẹ Ọlọrun ni ko gbadun igbeyawo wọn nitori fitinati awọn iyawo wọn – Mike Bamiloye - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, December 3, 2024

Ọpọ awọn ojiṣẹ Ọlọrun ni ko gbadun igbeyawo wọn nitori fitinati awọn iyawo wọn – Mike Bamiloye


Ogbontarigi oṣere tiata ẹlẹsin Kristiẹni nni, Alagba Mike Baloye ti sọrọ sita, o si ti jẹ ko di mimọ pe pupọ awọn to pe ara wọn ni iranṣẹ Ọlọrun ni ko gbadun igbeyawo wọn.

Mike Bamiloye sọ pe pupọ awọn iranṣẹ Ọlọrun yii ni iyawo wọn n fitinati ninu ile, ṣugbọn ti wọn ko le sọrọ sita.

Bamiloye to jẹ oludasilẹ Mount Zion Films Ministry naa lo sọrọ yii loju opo ikani ayelujara rẹ, niru ọrọ to kọ sita laipẹ yii.

Agba oṣere ọhun fi kun ọrọ rẹ pe awọn iyawo awọn ojiṣẹ Ọlọrun yii lo n hu iwa buruku naa nitori ti wọn mọ pe ọkọ wọn ko le lu awọn, tabi tu igbeyawo wọn ka.

Ọrọ yii lo si ti da awuyewuye silẹ lori ikanni ayelujara, koda, to ti ohun iwaasu lawọn ile ijọsin kaakiri.



No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI