Olu Orile-Ilawọ yan awọn oloye tuntun sile Ogboni - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Saturday, December 14, 2024

Olu Orile-Ilawọ yan awọn oloye tuntun sile Ogboni


Olu tiluu Orile-Ilawọn, Ọba Oluṣẹgun Alexandar MacGregor ti kede awọn oloye tuntun ti yoo di ile Ogboni ilu naa mu.

Bi ẹ ko ba gbagbe, ọjọ keji, oṣu kọkanla, ọdun 2024 ni Ọba MacGregor kede idaduro awọn oloye mẹwaa lori ẹsun tita ilẹ ilu nitakuta, leyi ti Kabiyesi sọ pe ko bojumu to fun idagbasoke.

Nigba to n kede awọn oloye tuntun naa, Kabiyesi jẹ ko di mimọ pe oun ti ṣagbeyẹwo awọn oloye naa daadaa, oun si rii pe wọn ko lẹbọ-lẹru lọwọ, ati pe wọn yoo ṣakoso ile Ogboni naa daadaa.

Nigba to n gba wọn lamọran, Ọba MacGregor ni ki awọn oloye naa rii daju pe wọn n ṣe awọn ohun to ba ofin ati ilana mu, ki wọn ma si ṣe awọn nnkan ti yoo ba orukọ ilu Ilawọ jẹ.

Kabiyesi ni ko si ipadasẹyin ninu awọn ti wọn rọ loye tẹlẹ, nitori ti wọn ko ṣetan lati ronupiwada, bẹẹ si ni wọn ko fẹẹ tẹriba fun ori ade.

Oloye Oluwole Dosunmu, Oluwo; Oloye Abraham Soyoye, Balogun; Oloye Fatai Sodimu, Jagunna. ati awọn meje miran ni Oba MacGregor ni ki wọn lọ rọkunnile lori awọn iwa aṣemaṣe ti wọn fi n tapa si ilu Ilawọ.

Kabiyesi ni awọn oloye tuntun naa yoo maa ri sọrọ Ile Ogboni titi digba ti wọn yoo fi yan awọn oloye yooku ti wọn yoo jọ maa ṣakoso.

Lara awọn oloye tuntun naa ni: Oloye Ishaq Adesanya to di Balogun; Oloye Rasheed Egberongbe to di Jagunna, Oloye Ayinde Onifade to di Baala, ati Oloye Akin Segun Bankoletoun di Aro.

Kabiyesi ni oun ko deede yan awọn wọnyi sipo lai ṣagbeyẹwo wọn finnifinni, o loun ti wo iwa wọn daadaa, toun si rii pe wọn yẹ, wọn si kaju oṣuwọn fun awọn ipo ọhun.

Bakan naa ni Ọba MacGregor tun kede awọn oloye tuntun ti wọn jẹ obinrin, awọn naa ni: Erelu Fatimo Kadejo to jẹ Osi Lika; Erelu Kofoworola Sulaimon to jẹ Omoriwafu; Erelu Jemilat Ayede toun jẹ Yeye Oge.

Awọn yooku ni: Erelu Muyibat Ọyaọṣọ toun jẹ Mosade; Erelu Ogundimu Popoola to jẹ Ajigbeda; ati Erelu Taiwo Adebayo toun jẹ Ẹkẹrin Lika.

Siwaju sii ni kabiyesi jẹ ko di mimọ pe ipo Oluwo ati awọn ipo miran si ṣi silẹ, nitori pe wọn kii deedee yan awọn eeyan lasan sibẹ.

Kabiyesi ṣalaye pe awọn eeyan gidi, ti wọn ni iwa rere laarin ilu, ti wọn si tun jẹ akikanju lo le di awọn ipo naa mu.

O ni lẹyin ti àwọn oloye tuntun yii ba ti bẹrẹ ijokoo nile Ogboni naa, wọn yoo mọ awọn to tọ s'awọn ipo to ṣi silẹ, foun lati buwọ lu wọn.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI