Okoowo ‘Real Estate’ kọja ọrọ ile kikọ nikan – Aarẹ EmmanuelKing, alaṣẹ Adron Homes - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, December 6, 2024

Okoowo ‘Real Estate’ kọja ọrọ ile kikọ nikan – Aarẹ EmmanuelKing, alaṣẹ Adron Homes


Alaṣẹ ati oludasilẹ gbajugbaja ileeṣẹ to n ṣowo ilẹ ati dukia lorileede Naijiria nni, Adron Homes and Properties Limited, Aarẹ Adetọla EmmanuelKing ti sọ pe okoowo tita ilẹ ati dukia ti a mọ si Real Estate kii ṣe lati maa kọ ile akọta nikan.

Oludasilẹ Adron Homes sọ pe ojuṣe awọn alakoso ileeṣẹ to n ta ilẹ ati dukia ni lati maa da agbegbe tuntun silẹ, nipa sisọ inu igbo di igboro to ni ọlaju.

Bakan naa ni Aarẹ EmmanuelKing jẹ ko di mimọ pe o ṣe pataki lati maa ṣagbekalẹ anfaani si eto ọrọ aje ti yoo mu idagbasoke ba igbe aye ọmọniyan nipa dida agbegbe tuntun silẹ.


Aarẹ EmmanulKing sọrọ yii nibi akanṣe eto awọn alakoso ileeṣẹ to n ta ilẹ ati dukia nipinlẹ Ọyọ, iyẹn Oyo State Real Estate Conference, akọkọ iru ẹ ti oludamọran pataki fun gominma lori ọrọ ile gbigbe ati idagbasoke igberiko, pẹlu ajọṣepọ ẹgbẹ Real Estate Developers Association of Nigeria (REDAN), nipinlẹ Ọyọ.

Nibi eto ọhun ti wọn pe akori rẹ ni “Positioning and Globalization of Oyo State Real Estate – Road to Urbanization,” ni ọpọ awọn agbaagba ati alẹnulọrọ lẹka eto gbigbe ti sọ pe o idagbasoke ṣe pataki.

Lara awọn to wa nibẹ ni igbakeji gomina ipinlẹ Ọyọ, Amofin Bayọ Lawal; oludamọran pataki fun gomina lori ọrọ ile gbigbe ati idagbasoke igberiko, Ọnarebu Akinṣẹtẹ Ọlakunle, to fi mọ gbogbo awọn alẹnulọrọ lẹka ile gbigbe.

Ninu ọrọ rẹ, Aarẹ Emmanuelking gbe oṣuba kare fawọn alakoso eto naa fun afojusun rere ti wọn ni lori ọrọ ile gbigbe ni Naijiria, pẹlu bo ṣe ni asiko to dara gan-an ni wọn ṣagbekalẹ eto ọhun.


“Agbekalẹ eto yii fi han pe ipinlẹ Ọyọ fi ara jin fun ọrọ idagbasoke ile gbigbe ati igberiko, paapaa okoo ile akọta. Ni Adron Homes, a ni iwuri lati wa ni iwaju lori afojusun yii, nipa mimu ayipada rere ba ẹka yii.”

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI