Ohun gbogbo ti yoo mu irọrun ba araalu lo jẹ wa logun - Ijọba Kwara - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, December 12, 2024

Ohun gbogbo ti yoo mu irọrun ba araalu lo jẹ wa logun - Ijọba Kwara


Ijọba ipinlẹ Kwara ti sọrọ idaniloju pe gbogbo ohun ti yoo mu igbe aye rọrun fun awọn ọmọ ati olugbe ipinlẹ naa lohun yoo maa dawọ le , fun wọn lati le jẹ mudundun eto iṣejọba awa-ara-wa.

Lara rẹ ni ti eto igbokegbodo ọkọ ọfẹ ti ijọba ṣagbekalẹ rẹ fawọn araalu, paapaa niluu Ilọrin to jẹ oluilu ipinlẹ naa.

Ijọba sọ pe gbogbo agbegbe ati ẹka ti araalu ba ti nilo ijọba ni ohun. yoo ti maa dide lati ṣe iranlọwọ lasiko.

Kọmiṣanna feto okoowo ati imọ ẹrọ, Ọnarebu Damilọla Yusuf Adelọdun lo sọ eyi di mimọ ni ọfiisi rẹ to wa niluu Ilọrin.

Nibẹ lo ti ṣalaye pe ẹgbẹẹgbẹrun araalu ni wọn n jẹ anfaani eto igbokegbodo ọkọ ọfẹ lọsẹ-ọsẹ ninu irin ajo to ti le ni ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹta kilomita.

O ṣalaye pe agbekalẹ naa ti mu irọrun ba ọpọ araalu, leyi ti wọn n fi imọriri wọn han si iṣakoso Gomina AbdulRahman AbdulRazaq.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI