Ọga ile-ẹkọ dero atimọle lori iku ọpọ eeyan n’Ibadan - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, December 20, 2024

Ọga ile-ẹkọ dero atimọle lori iku ọpọ eeyan n’Ibadan


Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ ti sọ pe ọga ile-ẹkọ girama ti awọn musulumi, Islamic High School, to wa lagbegbe Bashorun niluu Ibadan, Ọgbẹni Abdullahi Fasasi ti wa lahamọ awọn.

Ọjọru to kọja yii ni ileeṣẹ ọlọpaa sọ pe awọn ranṣẹ pe Fasasi lati wa sọ tẹnu rẹ lori ohun to ṣokunfa iku awọn ọmọde nibi apẹje ọdun ti Olori Naomi Silekunola to jẹ Olori ana fun Ọọni Ile-Ifẹ ṣagbatẹru rẹ.

Bo tilẹ jẹ pe AWIKONKO ko le fidi awọn to ku nibi ijamba naa mulẹ, ṣugbọn bawọn kan ṣe n sọ pe ogun eeyan ni, bẹẹ lawọn miran n sọ pe mejilelọgbọn lawọn to ku.

A gbọ pe bi wọn ṣe ranṣẹ pe ọga ile ẹkọ naa, ni wọn ti bẹrẹ sii fọrọ wa a lẹnu wo, ti wọn si tun fi sahamọ lori iṣẹlẹ ọhun.

Nnkan bi agogo mẹrin irọlẹ Ọjọru ni wọn ranṣẹ pe ọga ile ẹkọ girama yii, ti wọn si fi sahamọ ẹka ileeṣẹ ọlọpaa, iyẹn CID to wa ni Iayganku.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI