Oluwo tilu Iwo, Ọba Abdulrosheed Adewale Akanbi ti jẹ ko di mimọ pe ọba yoowu to ba n sin oriṣa ti dalẹ Olodumare.
Kabiyesi naa ni igbakeji oriṣa ni awọn ọba, paapaa ọba ilẹ Yoruba jẹ.
Ninu ọrọ rẹ to fi ranṣẹ sita lalẹ ọjọ Aiku to kọja yii, Telu akọkọ ṣalaye pe ọba ilẹ Yoruba nikan lo n jẹ orukọ papọ mọ Olodumare, fun idi eyi, wọn ko gbọdọ lọwọ si ibọriṣa kankan.
Oni Olodumare nikan lo n jẹ Ka-bi-ọ-ko-si, eyi lo fa ti ọba fi n jẹ igbakeji Olodumare.
Nidi eyi oni ọba to ba ti bọ oriṣa pọ mọ Olodumare ti dalẹ adaniwaye to gbe lọwọ ati pe aimọkan lo n fa.
O ni ti awọn lọba lọba ba mọ iyi ohun ti wọn gbe dani, wọn ko nii ba wọn bọ oriṣa, nitori awọn gan-an ni igbakeji Olodumare
Siwaju si, Kabiesi ni aini imọ to peye lo fa sababi ti awọn ọba alade fi n ṣe ẹbọ, ti wọn tun n bọ oriṣa.
No comments:
Post a Comment