Ọba MacGregor gba ilẹ abule marun ti awọn oloye ana ta danu fawọn ajoji n’Ilawọ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, December 19, 2024

Ọba MacGregor gba ilẹ abule marun ti awọn oloye ana ta danu fawọn ajoji n’Ilawọ


Pẹlu idunnu ati ayọ ni awọn ara abule marun-un ti awọn oloye kan ta ilẹ wọn nitakuta fawọn ajoji laipẹ yii, nigba ti wọn gbọ pe Kabiyesi wọn, Ọba Oluṣẹgun Alexander MacGregor ti gba awọn ilẹ naa pada.

Bi ẹ ko ba gbagbe, laipẹ yii ni iroyin jade sita wi pe Ọba MacGregor da awọn oloye mẹwaa duro lori ẹsun tita ilẹ ilu nitakuta fawọn ajoji, titapa si ori ade, ati aṣilo ipo.

Ile to le ni ẹgbẹrun kan ataabọ eeka (1600acres) ni wọn lawọn oloye naa ta pẹlu ifẹ ọkan ara wọn, lai jẹ ki kabiyesi naa mọ ohunkohun nipa rẹ.

A gbọ pe ki Kabiyesi naa too de ori aleefa lawọn oloye yii ti n ta awọn ilẹ naa, ti wọn ko si tun jawọ ni kete ti Ọba MacGregor gbọpa aṣẹ.

Latigba ti aṣiri ti tu sita ni igbesẹ ti bẹrẹ lati gba awọn ilẹ naa pada fun araalu.

Ọba MacGregor ninu ọrọ rẹ jẹ ko di mimọ pe “Bi a ba n ta ilẹ wa fawọn ajoji, ki ni yoo ku ti a le maa pe gẹgẹ bi orirun wa? Ilawọn kii ta ilẹ, a maa n ya awọn eeyan ni ilẹ, ti a si ma maa gba owo lọwọ wọn ni.

“Nigba ti a ba n ta ilẹ, a ti n le awọn ọmọ ilu danu niyẹn, Yoruba si sọ pe ile labọ sinmi oko. Nibo lawọn ọmọ ilu fẹẹ de si nigba ti a ba ti ta gbogbo ilẹ fawọn ajọji?” Kabiyesi sọ ninu ifọrọwerọ to ṣe pẹlu awọn akọroyin ni kete to rọ awọn oloye naa nipo.

Lẹyin ti Kabiyesi jawe lọ rọkunle fun wọn, lo tun paṣẹ pe ki wọn lọ ti Ile Ogboni ilu naa pa, titi digba ti gbogbo rogbodiyan to n ṣẹlẹ yoo fi dohun igbagbe.

Bi ẹ ko ba gbagbe, ninu iroyin ti a gbe jade laipẹ yii ni Kabiyesi jẹ ko di mimọ pe oun ti yan awọn oloye tuntun kan, ti wọn yoo maa ṣakoso Ile Ogboni ati gbogbo eto ilu.

Ni bayii, bo tilẹ jẹ pe iwadii awọn ọlọpaa ṣi n lọ lọwọ, sibẹ iroyin to tẹ wa lọwọ ti jẹ ko di mimọ pe Ọba MacGregor ti gba awọn ilẹ abule marun-un ti awọn oloye naa ta danu pada fawọn mọlẹbi to ni wọn.

Lara awọn abule ọhun ni: Abule Akia, Abule Ọṣọ, Abulẹ Ọla, ati Abule Ṣorẹmẹkun ti gbogbo wọn wa nijọba ibilẹ Ọdẹda.

Ọkan lara awọn ọmọ ilu to fi idunnu rẹ ha ṣalaye pe ọkan awọn ṣẹṣẹ balẹ ni latigba ti rogbodiyan naa ti bẹrẹ, to si lawọn ko lero wi pe awọn tun ṣi le sun oorun asundọkan mọ.

“Lati bi oṣu meloo sẹyin lati wa lẹnu wahala yii, awọn oloye kan niluu Ilawọ ni wọn ta ilẹ wa lọna aitọ, wọn fẹẹ le wa kuro labule wa, nibi ti a n pe ni ile.

“Nko le sun oorun asundọkan mọ, nitori pe niṣe lawọn janduku wa n le wa jade nile lojoojumọ, a ti lọ teṣan lọpọ igba lori rẹ, ṣugbọn alagbara ni awọn ti a n sọ yii, wọn n fi ọwọ ọla gba wa loju.

“Ọkan wa ṣẹṣẹ n balẹ bayii ni nigba ti a gbọ pe Kabiyesi ti bẹrẹ igbesẹ lati gba ilẹ wa pada.”

Agbẹnusọ aafin, Atanda Ọlọkọ to ba AWIKONKO sọrọ ṣalaye pe alaafia ilu Ilawọ ni Kabiyesi n wa, idi ree ti wọn fi n gba awọn ilẹ naa pada.

Ọlọkọ ni igba ọtun ti n pada silu Ilawọ nitori awọn igbesẹ ti Ọba MacGregor n gbe, to si jẹ ko di mimọ pe awọn araalu ti n fi idunnu wọn han.

“Bi mo ṣe n ba a yin sọrọ yii, abule marun-un ni kabiyesi ti gba ilẹ wọn pada ninu awọn abule ti wọn ti ta. Kabiyesi ko le laju silẹ ki awọn onimọ-tara-ẹni-nikan ba ilu jẹ mọ wọn lori.

“Gbogbo wa la mọ pe ko bojumu lati maa ṣe awọn nnkan ti ko gbe ilu larugẹ, fun idi eyi, atunto ati atunṣe ni kabiyesi n wa, lati mu ohun gbogbo pada bọ sipo.”

Bakan naa lo gbe oṣuba kare fun ijọba ipinlẹ Ogun lori ofin to de ilẹ tita ati ijiya to wa bi eeyan ba ta ilẹ lọna aitọ, eyi to lo ṣe iranwọ lori ilẹ tawọn oloye naa ta.

Bẹẹ lo sọ pe igbesẹ ọhun ko tii pari, nitori pe gbogbo ilẹ to ku ni wọn ṣi maa gba pada fawọn to ni wọn laipẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI