Igbimọ awọn ọba alaye niluu Ẹgba ti jawe gbele ẹ fun Ọba Taofeek Owolabi, Olu tiluu Ọbafemi lori awọn ẹsun aṣemaṣe ati titapa si ofin ti wọn fi kan an.
Lara awọn ẹsun ti wọn fi kan Ọba Owolabi ni tita ilẹ lọna aitọ, gbigba owo pẹlu ọgbọn alumọkọrọyi ati jibiti, to fi mọ riri awọn ori ade fin.
Ninu lẹta ti wọn kọ ranṣẹ si Ọba Owolabi lọjọ kẹtala, oṣu Kejila, alaga igbimọ ọba alaye naa, Ọba Adedotun Aremu Gbadebo, ẹni to tun jẹ Alake ti ilẹ Egba ti paṣẹ pe ki kabiyesi naa lọ rọkunile f’oṣu mẹfa gbako.
Alake ni lẹyin ti Taofeek ti kọ lati jẹ igbimọ naa nigba ti wọn kọ iwe ranṣẹ si, bakan naa ni ile igbimọ aṣofin naa tun ranṣẹ sii pẹlu, ṣugbọn to kọ lati yọju.
Wọn ni ko sohun miran ti wọn le ṣe ju pe ko kọkọ lọ rọkunle, ti awọn yoo si ma ṣe iwadii awọn ẹsun ti wọn fi kan an.
Saaju irọkunle naa, Oba Taofeek ti fi igbakan ri ṣe ijẹjọ ni ile ẹjọ Majisireti to wa ni Owode Egba ni inu osu Kẹwaa, latari pe wọn fi ẹsun kan an pe o gba owo ribiribi ni ona aitọ ni ọwọ enikan to n jẹ Michael Adeyemi.
Michael Adeyemi ni o fi ẹsun kan Taofeek pe o gba owo to to arunlelaadọrin miliọnu naira ni lọwọ oun, to si tun fiya jẹ ọlọpaa kan.
Nibayi, Alake ti ilẹ Ẹgba ti ni ki Ọba Taofeek lo sinmi sile naa.
Oba Taofeek ṣi n jẹjọ lori ẹsun mẹrin ọtọọtọ bii esun gbajuẹ, ibanija, igbimọ lilo ọgbọn arekereke gbowo ti wọn fi kan an.
No comments:
Post a Comment