Ijọba ipinlẹ Kwara ti kede wi pe awọn ja irawọ olukọ ile-ẹkọ ijọba ti Government Day Junior Secondary School, to wa lagbegbe Kulende, niluu Ilọrin, Hajia Fatimọh Hamzat Nike lori ẹsun aṣemaṣe.
Hajia Fatimọh Nikẹ ni olukọ ti wọn lu ọkan lara awọn agunbanirọ to n sin ilẹ baba rẹ nilẹ ẹkọ naa.
Oriṣiriṣi awuyewuye lo ti lọ kaakiri ori ayelujara latigba ti iṣẹlẹ ọhun ti jade sita.
Ninu atẹjade ti Kọmiṣanna fọrọ eto ẹkọ ati idagbasoke ọmọniyan, Hajia Sa’adatu Modibbo Kawu ati alaga ajọ to n ri sọrọ eto ẹkọ nipinlẹ naa, Mallam Bello Tauheed Abubakar buwọ lu loni, Ọjọru, wọn ni awọn ti ya irawọ olukọ naa pẹlu gireedi meji.
Yatọ si eyi, ijọba tun sọ pe olukọ naa yoo foju winna ofin lori bo ṣe tapa si ofin ilana eto iṣẹ ati ẹtọ ọmọniyan.
Ijọba jẹ ko di mimọ pe igbimọ oluwadii tohun dide lori ohun to ṣẹlẹ rii pe Hajia Hamzat Fatimoh Nike jẹbi ẹsun “jija lẹnu iṣẹ”.
“Igbimọ oluwadii ti a gbe dide lori iṣẹlẹ naa jabọ pe Hajia Hamzat Fatimoh Nike jẹbi ẹsun jija lẹnu iṣẹ, lilo ọrọ kugbakugbe, ọrọ abuku ati aibọwọ fun aami idanimọ orileede, eyi ti agunbanirọ naa ṣoju.
“Iwa rẹ tapa si ofin ilana iṣẹ ijọba, a si ti wa ja irawọ rẹ pẹlu gireedi meji.”
Bakan naa ni ijọba tun jẹ ko di mimọ pe awọn ti tare olukọ naa kuro ni ile-ẹkọ to wa bayii, lati lọ la isanilẹkọọ ati igbani-nimọran kọja.
Siwaju sii ni ijọba fi ye awọn araalu pe iru iwa ti Hajia Fatimọh naa hu ko nii jẹ itẹwọgba mọ rara, ti wọn si rawọ ẹbẹ si ajọ to n ṣakoso eto agunbanirọ ni Naijiria lati fọwọ wọnu.
“Ijọba kabamọ iwa ti olukọ naa hu gidi, ti a si n fi da ileeṣẹ eto agunbanirọ loju pe olukọ naa ko ṣoju iwa awọn ọmọ Kwara, ati pe iru iwa bẹẹ ko nii ṣẹlẹ mọ.”
Boya awon oluko ti o ku yi o fi eleyi kogbon
ReplyDelete