O pari! NAFDAC tun ṣawari ṣọọbu ti wọn ti n ṣayederu ọti mimu l’Ekoo - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, December 3, 2024

O pari! NAFDAC tun ṣawari ṣọọbu ti wọn ti n ṣayederu ọti mimu l’Ekoo


Ajọ to n ṣabojuto oun jijẹ ati oogun lorileede Naijiria, National Food and Drugs Agency of Nigeria (NAFDAC) ti sọpe awọn ti ṣawari ṣọọbu kan ti wọn ti n ṣayederu ọti mimu ti awọn araalu fẹran.

NAFDAC sọ pe agbegbe kan to wa ni Offin, adugbo Balogun ni Lagos Island ni wọn ti ṣawari ṣọọbu naa, nibi ti wọn ti n ṣe oriṣiriṣi ayederu ọti mimu.

Wọn ni awọn ṣiṣẹ iwadii naa lẹyin ti awọn kan ta ileeṣẹ wọn lolobo nipa ileeṣẹ ọhun.

Diẹ ree lara awọn fọto ibi iṣẹlẹ naa;





No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI