Asiko yii kii ṣe asiko to dun fun gbajugbaja oṣerebinrin nni, Mercy Aigbe lori bi ile rẹ olowo iyebiye ṣe jona di eeru.
Dukia to le ni obitibiti miliọnu naira lo jona pẹlu, gẹgẹ bi a ṣe gbọ.
Bo tilẹ jẹ pe a ko le sọ pato igba ti ile ọhun jona, ṣugbọn sibẹ, Mercy
funra rẹ sọ pe ko si ẹmi to sọnu sinu ijamba naa.
Ninu fọnran ti Mercy Aigbe gbe soju opo ayelujara kaakiri, eyi to fi ṣafihan
bi ile ọhun ṣe jona, Mercy loun dupẹ Ọlọrun wi pe ko ẹnikẹni ko ba ijamba naa lọ.
Titi di asiko ti a pari akojọpọ iroyin yii, awọn ololufẹ obinrin naa ṣi n
kii pẹlu, ti wọn si n gbadura fun un.
Ohun ti Mercy gbe jade ree:
No comments:
Post a Comment