Ọjọ buruku, eṣu gbomimu lọjọ ti awọn agbebọn kan yinbọn pa Pasitọ ijọ Royal Assembly Sanctuary to wa nipinlẹ Eko lasiko to n lọ sibi eto isinku.
Ajinigbe ni wọn pe awọn agbebọn ọhun ti wọn pa Apostle Ranti Ige-Daniel lagbegbe Isanlu to wa nijọba ibilẹ Yagba East, ipinlẹ Kogi.
Iroyin to tẹ wa lọwọ sọ pe niṣe ni wọn ji Pasitọ naa gbe laarin ilu Idọfin si Makutu, nitosi Isanlu.
Lara awọn to fi iṣẹlẹ naa to awọn akọroyin leti jẹ ko di mimọ pe lati ọjọ Iṣẹgun, ọsẹ to kọja lọhun ni pasitọ naa ti wa lagbegbe naa, nibi to ti lọ kopa nibi isọji to waye.
Wọn ni bo ṣe pari nibi isọji ọhun, lo gbera lati maa lọ sibi eto isinku kan to ti ni lerongba tẹlẹ.
Inu mọto ni wọn sọ pe Apostle Ige-Daniel wa ni nnkan bi agogo mẹjọ aabọ alẹ, lasiko ti awọn ajinigbe naa ya bo o.
Loju ẹsẹ la gbọ pe wọn ti dabọn bo mọto rẹ, ti ibọn naa si ba a. Loju ẹsẹ la gbọ pe o dagbere faye, ko to di pe awọn agbebọn naa ji awọn mẹta yooku ti wọn jọ wa ninu mọto ọhun gbe salọ.
Wọn ni obinrin kan to wa lara awọn mẹta naa ni igbagbọ wa pe yoo jẹ afẹsọna pasitọ yii.
Ọkan lara awọn ọrẹ pasitọ yii to sunmọ mọlẹbi rẹ, Rev Francis Iṣẹlowo sọ pe ajalu ati adanu nla ni iṣẹlẹ ọhun jẹ fun wọn.
Iṣẹlowo jẹ ko di mimọ pe miliọnu mẹwaa naira ni awọn ajinigbe ọhun n beere lori ẹni kọọkan, iyẹn awọn mẹta to wa lahamọ wọn silẹ.
No comments:
Post a Comment